Albertine N'Guessan Zebou Lou (ó di olóògbé ní 22 Oṣù Kẹẹ̀rin, Ọdún 2016) ti jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Côte d'Ivoire.

Albertine N'Guessan
Aláìsí(2016-04-22)Oṣù Kẹrin 22, 2016
Oumé
Orílẹ̀-èdèIvorian
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1981-2016

Ìsẹ̀mí rẹ̀ àtúnṣe

N'Guessan kẹ́kọ̀ọ́ ní National Institute of Arts (INA) ní ìlú Abidjan. Ní ọdún 1972, ó kópa pẹ̀lú Bitty Moro, Aboubakar Cyprien Touré àti Noël Guié nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les gens des marais, èyítí ònkọ̀tàn eré náà n ṣe Wọlé Ṣóyinká tí olùdarí rẹ̀ síì jẹ́ Jean Favarel. Ní ọdún 1977, N'Guessan kópa nínu eré The Tragedy of King Christophe, èyí tí Aimé Césaire kọ, tí olùdarí rẹ̀ síì jẹ́ Bitty Moro. Láàrin ọdun1986 sí 1987, ó kópa nínu eré Une femme à rent, eré tí Kodjo Ébouclé ṣe àgbéjáde rẹ̀ tí François Campeaux síì jẹ́ ònkọ̀tàn eré náà.[1]

Ní ọdún 1984, N'Guessan kópa nínu eré Ablakon, èyí tí Désiré Ecaré darí. Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó kópa nínu eré Visages de femmes láti ọwọ́ olùdarí kan náà.[2]

Ní ọdún 2000, N'Guessan kópa gẹ́gẹ́ bi ìyá sí Ossei nínu eré Adanggaman, èyí tí Roger Gnoan Mbala ṣe adarí rẹ̀.[3] Ó kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Sah Sandra ní ọdún 2009, gẹ́gẹ́ bi ìyáàgbà sí Sassi. N'Guessan ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olùkọ́ni ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga National Institute of Arts and Cultural Action tí ó wà ní ìlú Abidjan ṣáájú kí ó tó pinnu láti fẹ̀yìntì.[4] Wọ́n kàá kún ọ̀kan lára àwọn òṣèrébìnrin ìṣáájú ní orílẹ̀-èdè Côte d'Ivoire. Ní Oṣù Kẹfà, Ọdún 2015, wọ́n yẹ́ N'Guessan sí pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ Order of Merit of Culture and the Arts.[5]

N'Guessan papòdà ní 22 Oṣù Kẹẹ̀rin Ọdún 2016 ní ìlú Oumé, lẹ́hìn tí ó ṣàárẹ̀ ọlọ́jọ́gbọọrọ.[6]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀ àtúnṣe

 • 1981 : Adja Tio : À cause de l'héritage
 • 1984 : Ablakon
 • 1985 : Visages de femmes
 • 2000 : Adanggaman
 • 2007 : Nafi (TV series)
 • 2009 : Sah Sandra (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

 1. Messou, Charles (2015). "Albertine N'guessan et Thérèse Taba". Africultures. Retrieved 6 November 2020. 
 2. Appena, Marcel (27 April 2016). "Deuil : Rideau pour l’actrice Albertine N’Guessan !" (in French). Live.ci. http://live.ci/index.php?page=article&id_article=795. 
 3. "AN AFRICAN’S TAKE ON THE SHAMEFUL ‘TRADE’". 11 July 2001. https://nypost.com/2001/07/11/an-africans-take-on-the-shameful-trade/. 
 4. "Deuil/Cinéma : L’actrice ivoirienne Albertine N’Guessan est décédée". Abidjan.net (in French). 26 April 2016. Retrieved 6 November 2020. 
 5. Appena, Marcel (27 April 2016). "Deuil : Rideau pour l’actrice Albertine N’Guessan !" (in French). Live.ci. http://live.ci/index.php?page=article&id_article=795. 
 6. . 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde àtúnṣe