Ali baba
Arteen Ekizian ( wọ́n bí i ní September 28, 1901, ó sì dágbére fún ayé ní November 16, 1981), ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n mọ̀ ọ́n sí Ali Baba gẹ́gẹ́ bíi ìnagijẹ rẹ̀, ó jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ́-èdè Amẹ́ríkà, ògbójú abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tí ó sì ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹni tí ẹ̀ṣẹ́ rẹ̀ wúwo jù lágbàáyé (World Heavyweight Champion) tí ó gbajúgbajà ní sẹ́ńtúrì tí ó kọjá. [1][2][3]
ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Ekizian ní Samsun, Ottoman Empire kí ó tó lọ sí United states ní ọdún 1920 pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Garabed Massachusetts.[1]
Iṣẹ́
àtúnṣeEkizian bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjàkadì rẹ̀ nígbà tí ó fi wà nínú ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun ojú omi tí United States United States Navy. Ó jàjàjà títí tí ó fi gba àmì ẹ̀yẹ̀ àgbáyé ti àwọn ọmọ ogun orí omi World Champion Navy Wrestler, ní ọdún 1927, ni Ààrẹ orílẹ́-èdè Amẹ́ríkà Calvin Coolidge pè é sí ilé ìjọba White House láti yẹ́ ẹ sí. Ekizian bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọ́ṣẹ́ íjàkadì ní ọdún 1932 lẹ́yìn tí ó kúrò nínú ikọ̀ àwọn ọmọ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tí ó sì lọ sí Los Angeles. Ní April 24, 1936, Ekizian fi ẹ̀yìn ògbóǹtagí Dick Shikat na kẹ̀ ní ojú àwọn ènìyàn tí wọ́n tó 8,000 ní Detroit, Michigan tí ó sì borí rẹ̀. Ìjà àtúnjà fún àmì ẹ́yẹ àgbáyé yìí wáyé ní May 5 ní Madison Square Garden. Ekizian tún jáwé olúborí, níbẹ̀ ni wọ́n sì ti gbádé fún un gẹ́gẹ́ bí i abẹ́ṣẹ́kùbíòjò tí ó dáńtọ́ jù lágbàáyé. [1]
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeÓ gbé arábìnrin Alice Elizabeth Bagdoian níyàwó. Ọlọ́run sì bùkún ìgbéyàwó wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ mẹ́ta. Ekizian jẹ́ ẹlẹ́ṣin àwọn ọmọ lẹ́yìn Kìrìsìtẹ́nì. Christian.[1]
Àwọn àmì ẹ̀yẹ tí ó ti gbà àti àṣeyọrí rẹ̀
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 "The Legend of Ali Baba: The Incredible Story of Armenian Genocide Survivor & World Wrestling Champ Harry Ekizian". Ianyanmag.com. Retrieved September 23, 2017.
- ↑ "Ali Baba & His Forty Lives:
Harry Ekizian's Saga of Survival and Success". Wideasleepinamerica.com. Retrieved September 23, 2017. - ↑ "A Hollywood Movie in Waiting: The Tale of Ali Baba - the Home of Historical Wrestling". Archived from the original on March 22, 2017. Retrieved March 21, 2017. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "World Heavyweight Title [NYSAC]". Wrestling-Titles.com. Retrieved 23 September 2017.
- ↑ "World Heavyweight Title". Wrestling-Titles.com. Retrieved 23 September 2017.