Aliyu Magatakarda Wamakko

Olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
(Àtúnjúwe láti Aliyu Wamakko)

A bí Aliyu Magatakarda Wamakko ní ọjọ́ kínní, Oṣù Kẹ́ta, Ọdún 1953. Ní Ọdún 2007, nínú Oṣù kẹẹ̀rin wọ́n dìbò yàn-án sí ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ṣókótó, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́ni tó ń ṣe aṣojú ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party, (PDP). Ẹgbẹ́ yìí ni a mọ̀ sí ẹgbẹ́ Òní "umbrella".

Aliyu Magatakarda Wamakko
Governor of Sokoto State
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
29 May 2007
AsíwájúAttahiru Bafarawa
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí1 March 1953
Wamakko, Sokoto State, Nigeria

Ètò-ẹ̀kọ́ ati iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn Olùkọ́ni tí a mọ̀ sí Teachers' College, nilùú Ṣókótó, láàrín ọdún 1968 sí ọdún 1972, léyìí tó lo ọdún márùn ún gbáko. Lẹ́yìn tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ni láàrín ọdún 1973 sí 1977, kó tó wá lọ sí Ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì, Univercity of Pittsburgh ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó parí ẹ̀kọ́ Fásitì, ó sì gboyè B.Sc. ní oṣù kẹjọ, ọdún 1980. Ó padà sí Ilẹ̀ Nàìjíríà, o ṣiṣẹ́ akẹ́ẹ̀kọ́ níle ẹ̀kọ́ olùkọ́ni, ìyẹn Teachers'

College. Wamakko, ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ Ìjọba Ìbílẹ̀ Zumi mi gẹ́gẹ́ bíi igbákejì akọ̀wé. Wọ́n gbéga lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ lọ sípò adelé akọ̀̀̀̀̀̀̀̀̀̀̀̀̀̀̀wé. Ó tún ṣiṣé ní ìjọba ìbílẹ̀ Kaura Namoda. Wọn yan sípò Alága ìjọba Ìbílẹ̀ Ṣókótó, láti ọdún 1986 sí ọdún 1987. Wamakko di ọ̀gá pátápátá ilé iṣẹ́ ibi Igbafẹ́ fáwọn arìnrìn-àjò àti ilé ìtura, ní Ṣókótó. Ní ọdún 1992, oṣù kẹ́ta, Wamakko ní ìgbéga sí ipò Olùdari àgbà fún àwọn àkànṣe iṣẹ́, ní ọ́fíìsì Gọ́mìnà, ní Ìpinlẹ̀ Ṣókótó.

Ètò ìṣèlú rẹ̀

àtúnṣe

Ní ọdún 1999, Wamakko di igbákejì Gómìnà Attahiru Bafarawa ti Ìpínlẹ̀ Ṣókótó nínú ẹgbẹ́ òṣèlú, All Nigeria Peoples' Party (ANPP). Ẹ̀wẹ̀, àwọn ará ìlú dìbọ̀ yan-an lẹ́lẹ́ kejì sípò Igbákejì Gómìnà, ní oṣù kẹ́rin, ọdún 2003. Ó kọ̀wé fipò Igbákejì Gómìnà sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù kẹ́ta, ọdún 2006. Nínú oṣù kẹ́rin, ọdún 2007, ni Wamakko díje fún ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ṣókótó lábẹ àsíá People's Democratic Party, ó sì jáwé olúborí. Ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kaàrún, ọdún 2007, ni Gómìnà Wamakko bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà .[1]

Àmọ́ ṣá, ní oṣù kẹẹ́rin, ọdún 2008, ni ìwé ìpèjọ́ dé, tí wọ́n sì fagilé èsì ìdìbò Gómìnà Wamakko nítorí wípé, ó wà nínú ẹgbẹ́ All Nigeria Peoples Party, (ANPP), nígbà tí ó lọ díje dupò Gómìnà, tó sì pegedé lórí ẹgbẹ́ àsíá People's Democratic Party, (PDP). Ilé-ẹjọ́ pàṣẹ pe kí Abdullahi Balarabe Salame, bọ́ sípò adelé Gómìnà, láti ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹẹ̀rin, sí ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù kaàrún, ọdún 2008, (11 April - 28 May 2008), ti àwọn elétò ìdìbò fi tún ètò ìdìbò míràn ṣe.

Ètò ìdìbò láàrín Wamakko àti Muhammadu Maigari Dingyadi tó díje láti ẹgbẹ́ DPP, pẹlú Wamakko àti Attahiru Bafarawa, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú DPP. Wamakko tún jáwé olúborí lẹ́lẹ́kejì, sípò Gómìnà ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìlú nínú oṣù kaàrún ọdún 2008. Olùdíje ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá sọ wípé òun yóò tún gbalé ẹjọ́ lọ láti lọ takò èsìGomiGomGomingomi. Ní ọdún 2007, Wamakko ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò léṣẹ̀ẹ́wọ̀gbẹ́ tí a mọ̀ sí State Poverty Reduction Agency, (SPORA), láti pèsè iṣẹ́ fàwọn ọ̀dọ́. Nínú oṣù lasan, ọdún 2009, ó tún ṣe ìpèsè ilé gbígbé bíi ẹgbẹ́ẹ̀rún méjí fáwọn ará ìlú. Síwájú sii, ó sàlàyé wípé òun kò ní dá ilé ìfowópamọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìjọba òun yóò ṣàtìlẹ́yìn fún ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ síi. Ní oṣù kẹẹ̀wá, ọdún 2009, kọmíṣọ́́́́nà fún ètò ìgbẹ́jọ́ ní ìpínlẹ̀ sọ wípé wọ́n ṣetán láti ṣe ìwáàdí Gómìnà, tẹ́lẹ̀rí Attahiru Bafarawa àti àwọn Márùn míràn fún ìwà àjẹbánu àti ìṣe-owó ìlú tó tó bílíọ́nù Mẹ́ta Naira (N2.919 billion), mọ́ku-mọ̀ku nígbà tí ó wà lórí ipò Gómìnà. Bafarawa pe akiyesi àwọn àjọ olùwáàdi tí Gómìnà Wamakko ti ìpínlẹ̀ Ṣókótó, pé wọ́n fẹ́ṣe àtakò oun àti iṣẹ́ tí oun ṣe, nígbà tí oun wà lórí àga Gómìnà tẹ́lẹ Ó sọ síwájú síi pé, Wamakko ni igbákejì òun, nígbà tí òun jẹ́ Gómìnà, ó gba ìgbìmọ̀ olùwáàdi kí wọ́n ránṣẹ́ sí Wamakko kí ètò ìwáàdí tó le è bẹ̀rẹ̀. Àwọn olùwáàdi wòye pé ọ̀rọ̀ náà ti di ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí kò ṣe fọwọ́ bù.


Àwọn itọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Governor Aliyu Magatakarda Wamakko of Sokoto State". Nigeria Governors Forum. Retrieved 2009-12-05.