Alphonse Kotiga
Colonel Alphonse Kotiga, tí àwọn míràn mọ̀ sí Kotiga Guérina, jẹ́ olóṣèlú àti ọmọ ológun ọmọ orílẹ̀ ède Chad. Ó wà lára àwọn tí ó dìtẹ̀ gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Chad François Tombalbaye ti o sì ṣekú pa á ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù kẹrin ọdún 1975, ó sì di ọkàn lára àwọn mínísítà ìjọba ààrẹ Félix Malloum tí ó gun orí àléfà lẹ́yìn èyí.
Ìlú abínibí rẹ̀ ni Moyen-Chari, ó kó lọ sí gúúsù Chad lẹ́yìn ìgbà tí ìjọba Malloum dàrú ní ọdún 1979. Níbẹ̀ ni ó ti di adarí ẹgbẹ́ alátakò, Red Codos, ṣùgbọ́n ó padà pẹ̀tù sí ìjà rẹ̀ pẹ̀lú ìjọba Hissène Habré ní ọdún 1986.