Alvin Law (tí a bí ní ọdún 1960, ní ìlú Yorkton, Saskatchewan) jẹ́ asọ̀rọ̀ ìwúrí àti olóòtú ètò orí rédíò.[1]

Alvin Law
Ọjọ́ìbí1960
Yorkton, Saskatchewan
Iṣẹ́Motivational Speaker, radio broadcaster, Musician

Wọ́n bí Law láìlápá nítorí oògùn thalidomide tí ìyá rẹ̀ lò nígbà tí ó wà nínú oyún. Àwọn òbí rẹ̀ gbé fún àwọn tó máa ń gba ọmọ ọlọ́mọ tọ́, èyí ló sì mú kí Hilda àti Jack Law gba ọmọ náà tọ́.

Law kọ́ bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ọ̀jọ́ ẹni nípa lílo ẹsẹ̀ nìkan, lára àwọn iṣẹ́ tó máa ń fi ẹsẹ̀ ṣe ni oúnjẹ jíjẹ, aṣọ wíwọ̀, àti ìtọ́jú ara ẹni, wíwa ọkọ̀ aṣọ rírán, eré-ìdárayá ṣíṣe, lílu dùrù àti àwọn ohun èlò orin mìíràn. Ilé-ìwé tí àwọn ọmọ yòókú tí nǹkan kan ò ṣe ni ó lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn ilé-ìwé fún ọmọ tí ò lápá wà ní ìlú náà, àmọ́ àwọn òbí tó gbà á tọ́ fẹ́ láti fi sí ilé-ìwé tí gbogbo ènìyàn ń lọ.

Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ó jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olóòtú lórí rédíò. Ó ṣe èyí títí tí ó fi bẹ̀rẹ̀ ètò ṣíṣe lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, àmọ́ àwọn tó ń rí sí ètò yìí ò mọ bí àwọn ará-ìlú ṣe máa gba ètò tí ẹni tí ò lápá ṣe.

Law bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ ìwúrí ní ọdún 1981. Ní ọdún 1988, ó sọ èyí di iṣẹ́ tó yàn láàyò gan-an, ó sì ṣe ìdásílẹ̀ AJL Communications Ltd. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ méjì, òun sì ni òǹkọ̀wé Alvin's Laws of Life: 5 Steps To Successfully Overcome Anything. Ó sì tún kópa nínú eré-ṣíṣe, ọ̀kan lára àwọn fíìmù tó kópa nínú rẹ̀ ni X-Files, níbi tí ó ti ṣe ẹ̀á-ìtàn oníwàásù.[2]

Ní ọdún 1986, Law díje dupò ìjọba kan lábẹ́ àsíá Party Conservative Party Saskatchewan nígbà ìdìbò ọdún 1986, àmọ́ John Solomon tí wọ́n jọ díje dupò yìí ni ó wọlé.

Law ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìgbìmọ̀ ti Canadian Association of Professional Speakers. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún Law jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí ètò Telemiracle tó máa ń wá́yé ní ọdọọdún.

Ní ọdún 2018, Law jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó wà ní Canadian Disability Hall of Fame.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe

Àwọn ìwé tó kọ

àtúnṣe
  1. Empty citation (help) 
  2. "Calgary's Alvin Law featured in documentary on ongoing Thalidomide tragedy". 
  3. "Canadian Disability Hall of Fame". Canadian Foundation for Physically Disabled Persons. Retrieved 30 October 2018.