Amaka Igwe

Nigerian Filmmaker & Creative Industries Stakeholder Champion


Amaka Igwe (tí a bí ní ọjọ́ kejì oṣù Ṣéẹ́rẹ́ ọdún 1963 - ó di olóògbé ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Igbe, ọdún 2014). Amaka Igwe jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà àti ọ̀gá sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. Òun ni aláṣẹ iléeṣẹ́ rédíò Top 90.8 Èkó àti iléeṣẹ́ Amaka Igwe Studio. Ipa rẹ̀ lásìkò ìgbédìde fíìmù àgbéléwò láyé sinimá ní Nàìjíríà kò ṣé é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Èèkàn ní ni agbo òṣèré nígbà ayé rẹ̀ kí ó tó di wí pé àìsàn ikọ́ sémìísémìí mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ.. [1]

Ní ọjọ́ kejì, Oṣù Ṣéẹ́rẹ́ wọ́n dá ṣe ìrántí ọjọ́ọ̀bí rẹ̀, wọ́n sì fi Google Doodle da lọ́la. . [2] [3] [4]

Ibẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Uzomaka Audrey "Amaka" Igwe jẹ́ ọmọ Isaac àti Patience Ene ní ìlú Port-Harcourt. Ipo karùn-ún ni Igwe nínú àwọn ọmọ méje, ó sì jẹ́ ọmọbìnrin kẹrìn nínú obìnrin mẹ́fà. "GCO" Ọ̀gá Apàṣẹ̀ ni bàbá rẹ̀ máa  ń pè é, tí ìyà rẹ̀ sì ń pè é ni "ìjì" (storm) torí pé ọwọ́ rẹ̀ kì í dilẹ̀. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ All Saints àti Iléẹ̀kọ́ Gíga Awkunanaw àwọn obìnrin ní Enugu.

[5] Ó ja ẹ̀ṣẹ́, ó gba bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá, òun sì ni olórí ikọ̀ agbábọ́ọ́lù àwọn obìnrin. Nígbà tí ó ń ṣe A-level ní Kọ́lẹ́jì Idia, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àwárí ẹ̀bùn rẹ̀. Ó kọ́ àwọn èèyàn ní ijó Atilogwu,ó sì díjé orílẹ̀èdè. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ eré-onítàn àti orin. Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ òfin ló wu Amaka Igwe láti ṣe ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ Ajọ́ JAMB fún ní *Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ àti Ẹ̀sìn (Theology). Fún ìdí èyí, ó kẹ́kọ̀ọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ àti Ẹ̀sìn náà ní Yunifásítì Ifẹ̀ (Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ báyìí)

Láti OAU, Igwe darapọ̀ mọ́ MNET short celluloid film "Barbers Wisdom" gẹ́gẹ́ bíi olùdarí, ó tẹ̀síwájú láti lọ sí Yunifásítì Ìjọba Àpapọ̀ tí ìlú Ìbàdàn, níbi tí ó ti gba òye EM-EE (MA) nínú Ìmọ̀ Library and Information Sciences. Lásìkò tí ó jẹ́ àgùnbánirọ̀ ó jẹ́ akọ̀wé arìnrìn-àjò fún Scripture Union. Ó sì ṣíṣe gẹ́gẹ́ bíi Aláṣẹ olùdarí ní Iléẹ̀kọ́ Yunifásítì Ìmọ̀ Èrọ Anambra ni Eida Information Systems kí ó tó fi àdàgbà ètò rọ̀ sí agbo àwọn alátinúdá

à. Ó fẹ́ ọkọ rẹ̀ Charles Igwe ní Oṣù Igbe ni ọdún 1993, wọ́n sì bí ọmọ mẹ́ta.

[6]

Iṣẹ́

àtúnṣe

Aláṣeyorí òǹkọ̀wé, olótùú, olùdarí, oníṣòwò àti olùkọ́ ni Igwe. Aṣáájú Fíìmù àti Dirama ayé òde òní tí Nàìjíríà ni. Ó di gbajúgbajà gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀tàn àti olótùú eré "Checkmate" àti *Fuji House of Commotion". Lára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ni Nollywood ni Rattle snake àti Violated tí ó ya iléeṣẹ́ Amaka Igwe Studio sọ́tọ̀ lásìkò fíìmù àgbéléwò láyé sinimá ní Nàìjíríà. Òun ló dá BOBTV Exp sílẹ̀, Òun sì ni olùdásílẹ̀ àti Aláṣẹ Rédíò TOP 90.9Fam tó wà ní ìgboro Èkó, The quality content production House, Amaka Igwe Studios àti Q Entertainment Networks and ìkànnì DSTV.

Ohun Ìní

àtúnṣe

Àwùjọ kò ní gbàgbé ipa ribiribi tí Igwe kò láti mú ìgbéga bá fíìmù ṣíṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kò ka agbo òṣèré sí pàtàkì nígbà kan, síbẹ̀ Iléeṣẹ́ Amaka Studio gbìyànjú púpọ̀ láti mú ìdàgbàsókè ba, àti àṣeyọrí kí wọ́n sì jẹ́ ìwúrí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn òṣèré nílẹ̀ Nàìjíríà, àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà àti àgbáyé lápapọ̀.


Ìbẹ̀rù àti ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, àwọn ẹbì rẹ̀, àṣeyege, iṣẹ́ gidi rẹ̀, àti àṣà lákòótán jẹ́ àbùdá pàtàkì Amaka. Ó fẹ́ràn àwọn ẹ̀bí rẹ̀, ó sì pinnu láti má fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kankan. Amaka Igwe mú ìdàgbàsókè ba awon èèyàn, àwọn sì ni ẹ̀rí rẹ̀ dòní. Ó sábà máa ń sọ fún àwọn tí ó ń kọ́ níṣẹ́ tààrà pé òun yóò fi ohunkóhun tí òun bá ní ṣe àlékún òun ti o wà lọ́wọ́ tiwọn kí wọ́n lè dára ju òun lọ. Kò hùwà àfèmi-àfèmi, ó sì farajìn fún ìdàgbàsókè àti ìsọlọ́jọ agbo àwọn alátinúdá.



. [7]

Ọlá ati oriyìn

àtúnṣe

Igwe gba àwọn àmì-ẹ̀yẹ nígbà ayé rẹ̀. Ní ọdún 2011, Orílẹ̀èdè Nàìjíríà fi oyè MFR - Ọmọ Ẹgbẹ́ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà (Member of the Federal Republic of Nigeria) da lọ́lá fún ìmọrírì akitiyan àti ipa pàtàkì rẹ̀ sí àwùjọ àwọn alátinúdá.

Ni ọjọ́ kejì, Oṣù Ṣéẹ́rẹ́, Google fi Google Doddle ṣe àjọyọ ọjọ́ọ̀bí Kẹtàdínlọ́gọ́ta fún un


ria." [8] [9]

. [10] [11]

Igwe kú ní Enugu ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, Oṣù Igbe ọdún 2014, ni alẹ́ aago mẹ́jọ àbọ̀. Gbogbo ìgbìyànjú láti dóòlà ẹmí rẹ̀ lọ́wọ́ pípeléke ikọ́-sèmìí-sèmìí tí ó ń bá fínra ló já sí pàbó. Gómìnà Ìpínlẹ̀ Imo nígbà náà Rochas Okorocha lọ sí ètò ìsìnkú rẹ̀, bákan náà ni àwọn èèkàn ní agbo àwọn òṣèré.


8:30 , [12] [13] [14] [15]

Àkójọpọ̀ Fíìmù

àtúnṣe
  • Rattle Snake 1,2 & 3
  • Violated 1 & 2
  • To Live Again
  • Full Circle
  • A Barber's Wisdom

Eré Tẹlifíṣàn

àtúnṣe
  • Fuji House of Commotion
  • Solitaire
  • Now We Are Married
  • Infinity Hospital
  • Bless This House
  • Checkmate

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe

Iwe itan-akọọlẹ

àtúnṣe