Amal Bedjaoui
Amal Bedjaoui (tí a bí ní 27 Oṣù Keèje, Ọdún 1963) jẹ́ olùdarí eré, agbéréjáde, àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Àlgérià.
Amal Bedjaoui | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 27 Oṣù Keje 1963 Algiers |
Orílẹ̀-èdè | Algerian |
Iṣẹ́ | Screenwriter, film producer, film director |
Notable work | Un fils (2003) |
A bí Bedjaoui ní Algiers, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ fíìmù ṣíṣe ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York University. Ó parí ní ẹ̀ka Institut des hautes études cinématographiques ti ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà. Lẹ́hìn náà, ó gba oyè gíga nínu ìmọ̀ sinimá láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga <i>Paris 1 Pantheon-Sorbonne</i> ní ọdún 1987.[1] Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó ṣiṣẹ́ bíi amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún dídarí àti ìṣàkóso gbígbé fíìmù jáde. Àkọ́kọ́ fíìmù oníṣókí rẹ̀ tí ó gbé jáde ni Une vue imprenable, ní ọdún 1993. Ẹ̀kejì fíìmù oníṣókí rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ ń ṣe Shoot me an Angel jẹ́ gbígbé jáde ní ọdún 1995, ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ ti Panorama níbi ayẹyẹ Berlin International Film Festival.[2]
Ní ọdún 2002, ó dá ilé-iṣẹ́ agbéréjáde kan sílẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ n ṣe ML Productions. Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó darí fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Un Fils,[3] èyí tí n sọ ìtàn ọ̀dọ́mọdékùnrin kan àti ìbálòpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Ìyáàfin kan.[4] Fíìmù náà jẹ́ títọ́kasí gẹ́gẹ́ bi fíìmù tó lòdì sí àwọn òfin ìbálòpọ̀.[5]
Bedjaoui jẹ́ ọmọ olóṣèlú Mohammed Bedjaoui.[6]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "AMAL BEDJAOUI". Mlproductions.fr (in French). 19 February 2015. Archived from the original on 19 February 2015. Retrieved 1 October 2020.
- ↑ "Filmographie d'Amal Bedjaoui". Africultures (in French). Retrieved 1 October 2020.
- ↑ "AMAL BEDJAOUI". Mlproductions.fr (in French). 19 February 2015. Archived from the original on 19 February 2015. Retrieved 1 October 2020.
- ↑ Nicklaus, Olivier (13 June 2007). "UN fils d'amal Bedjaoui". Inrockuptibles (in French). Retrieved 1 October 2020.
- ↑ Sensuous Cinema: The Body in Contemporary Maghrebi Film. 2018.
- ↑ Bedjaoui, Mohammed (1993). The New World Order and the Security Council: Testing the Legality of Its Acts. Martinus Nijhoff Publishers. ISBN 0792334345.