Amane Beriso
Amane Beriso Shankule ni a bini ọjọ kẹtala, óṣu October, Ọdun 1991 jẹ̀ elere sisa lobinrin ilẹ Ethiopia. Ni ọdun 2022, Arabinrin naa kopa ninu Marathon ti Valencia ni bi to ti gbe ipo kẹta[1].
Òrọ̀ ẹni | |
---|---|
Orúkọ kíkúnrẹ́rẹ́ | Amane Beriso Shankule |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Ethiopian |
Ọjọ́ìbí | 13 Oṣù Kẹ̀wá 1991 |
Sport | |
Orílẹ̀-èdè | Ethiopia |
Erẹ́ìdárayá | Sport of athletics |
Event(s) | Long-distance running |
Coached by | Gemedu Dedefo |
Achievements and titles | |
Personal best(s) |
|
Aṣèyọri
àtúnṣeAmane Beriso yege ninu Idaji Marathon ti Copenhagen ni Ọdun 2014. Ni ọdun 2015, Amane yege ninu Idaji Marathon ti Roma-Ostia pẹlu wakati 1:08:43. Ni ọdun 2016, Arabinrin naa kopa ninu Marathon ti ilẹ Dubai pẹlu wakati 2:20:48 nibi to ti gbe ipo keji. Ni ọdun 2017, Amane yege ninu Marathon ti Prague pẹlu wakati 2:22:15. Ni ọdun 2020, Amane yege ninu Marathon ti Mumbai pẹlu wakati 2:24:51[2]. Ni óṣu August, ọdun 2022, Amane yege ninu Marathon ti Mecico City pẹlu wakati 2:25:05[2]. Ni ọjọ kẹrin, óṣu December, ọdun 2022, Arabinrin naa yege ninu Marathon ti Valencia pẹlu wakati 2:14:58[3][4].