Amarachi

Akọrin obìnrin

Amarachi Uyanne ( wọ́n bí ní 17 Oṣù kèje, 2004), ó gbajúgbajà gẹ́gẹ́ bí i Amarachi, ó jẹ́ ọmọdé-ọ̀dọ́ olórin Nàìjíríà, oníjó a sì tún mọ̀ ọ́ fún ìlò irinṣẹ́ violin rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí i olúborí ìdíje Naigeria's Got Talent tí àwọn ọ̀dọ́.[1][2]

Amarachi
Background information
Orúkọ àbísọAmarachi Uyanne
Ọjọ́ìbí17 Oṣù Keje 2004 (2004-07-17) (ọmọ ọdún 20)
Ìpínlẹ̀ Delta, Nàìjíríàq
Irú orinAfropop, hip hop
Occupation(s)Oníjó
InstrumentsOrin kíkọ, violin
Years active2012–ó ń lọ
Associated acts

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀

àtúnṣe

Amarachi jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà. Wọn tọ dàgbà ní Ìpínlẹ̀ Ẹdó, ní ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jó láti ọmọ ọdún 5.[3] Ní 2012, ó tayọ gẹ́gẹ́ bí i olúborí ìdíje àkọ́kọ́ Nigeria's Got Talent pẹ̀lú ẹ̀bùn owó N10,000,000. Èyí fà á kí wọ́n ma pè é ní "oní mílíọ̀nù kékeré Naijiria". [4]

Ẹ̀kọ́ Kíkọ́

àtúnṣe

Ó lọ ilé-ẹ̀kọ́ University Preparatory Secondary School ní ìlú Benin, Ìpínlẹ̀ Ẹdó. Olókìkí ọmọ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ kàwé gboyè ní ilé-ìwé náà ní oṣù kèje, 2019. Tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dára pọ̀ mọ́ ilẹ̀-ẹ̀kọ́ gíga Benson Idahosa University, Benin, Ìpínlẹ̀ Ẹdó, Nàìjíríà.

Iṣẹ́

àtúnṣe

After emerging as the winner of Nigeria's Got Talent, Amarachi released her debut single titled "Amarachi Dance". Bí ó di olúborí ìdíje Nigeria Got Talent, Amarachi ṣe àgbéjáde orin àkọ́kọ́ rẹ̀ "Amarachi Dance".[5] Ó tún tẹsíwájú láti fi olórin Phyno sínú orin rẹ̀ "Ova Sabi", orin rẹ̀ tà gan-an bẹẹ̀ ó gbá àwọn ìwúrí tó tẹ́rùn láti ọwọ́ àwọn lámèyító ajẹmọ́rin.[6] Lọ́wọ́lọ́wọ́ ó ń dára Amarachi Talent Academy, ilé-ẹ̀kọ́ tí wọ́n tí ń kọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n ní ẹ̀bùn ijó àti orin bí wọ́n ṣe le dàgbà sókè.[7]

Àgbàjọ Orin

àtúnṣe
  • "Amarachi's Dance"
  • "Get Down"
  • "Ova Sabi" (Ft Phyno)
  • "Te Quiero"

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "N10m Up For Grabs at Nigeria's Got Talent 2". P.M. News. October 9, 2013. http://www.pmnewsnigeria.com/2013/10/09/n10m-up-for-grabs-at-nigerias-got-talent-2/. Retrieved September 18, 2015. 
  2. Akan Ido (December 10, 2012). "Exclusive: 7 questions for Amarachi Uyanne, who won 'Nigeria's Got Talent' yesterday". YNaija. http://ynaija.com/exclusive-7-questions-for-amarachi-nyanne-who-won-nigerias-got-talent-yesterday/. Retrieved September 18, 2015. 
  3. Benjamin Njoku; Anozie Egole (December 22, 2012). "AMARACHI UYANNE Ready to fly". Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2012/12/amarachi-uyanne-ready-to-fly/. Retrieved September 18, 2015. 
  4. Damilare Aiki (December 10, 2012). "Meet Nigeria's Youngest New Millionaire! 8 Year Old Dancing Sensation, Amarachi Uyanne Emerges Winner of Nigeria's Got Talent – Wins 10 Million Naira". BellaNaija. http://www.bellanaija.com/2012/12/10/meet-nigerias-youngest-new-millionaire-8-year-old-dancing-sensation-amarachi-uyanne-emerges-winner-of-nigerias-got-talent-wins-n-10-million/. Retrieved September 18, 2015. 
  5. Osagie Alonge (June 21, 2013). "NETPod: Nigeria's Got Talent winner debuts music single". Nigerian Entertainment Today. http://thenet.ng/2013/06/netpod-nigerias-got-talent-winner-debuts-music-single/. Retrieved September 18, 2015. 
  6. "VIDEO: Amarachi – Ova Sabi ft. Phyno". NotJustOk. March 19, 2015. Archived from the original on March 23, 2017. Retrieved September 18, 2015. 
  7. Amaka Ojo (October 16, 2013). "Nigeria's Got Talent winner Amarachi sets up talent academy". Nigerian Entertainment Today. Archived from the original on July 26, 2015. https://web.archive.org/web/20150726201449/http://thenet.ng/2013/10/nigerias-got-talent-winner-amarachi-sets-up-talent-academy/. Retrieved September 18, 2015.