Amelia Umuhire
Amelia Umuhire (tí wọ́n bí ní ọdún 1991) jẹ́ olùdarí eré, agbéréjáde, àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Rùwándà àti Jẹ́mánì.
Amelia Umuhire | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1991 (ọmọ ọdún 32–33) Kigali |
Orílẹ̀-èdè | Rwandan-German |
Iṣẹ́ | Film director, producer, screenwriter |
Ìgbà iṣẹ́ | 2015-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeUmuhire ni ẹni tí wọ́n bí ní ìlú Kìgálì, orílẹ̀-èdè Rùwándà ní ọdún 1991. Ó ní àwọn ọmọìyá méji kan tí wọ́n ṣe Anna Dushime àti Amanda Mukasonga. Ìyá rẹ̀ tí n ṣe Esther Mujawayo jẹ́ ajìjàgbara àti oníwòsàn.[1] Ní àkókò ìpa-ẹ̀yà-run tí ó wáyé ní orílẹ̀-èdè Rùwándà ní ọdún 1994, wọ́n ṣekú pa bàbá rẹ̀ àti àntí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Tutsi.[2] Wọ́n gbe Umuhire sá lọ sí orílẹ̀-èdè Jẹmánì níbi tí ó ti lọ àwọn ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rè rẹ̀ tí wọ́n sì fun ní ànfàní láti di ọmọ-oníìlú. [3] Umuhire ka àwọn ìwé rẹ̀ ni ìlú Vienna àti ní ìlú Berlin.[1]
Ní ọdún 2015, ó ṣe adarí eré fún ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú dídarí eré Polyglot . Eré náà gba àmì-ẹ̀yẹ. Umuhire tún ti darí fíìmù oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mugabo ní ọdún 2016. Wọ́n ṣètò fíìmù náà ní ìlú Kìgálì, ó síì dá lóri ẹnìkan tí ó ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Rùwándà fún ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀ láti ìgbà ìpa-ẹ̀yà-run ti ọdún 1994.[4] Òun náà ló ṣe adarí fídíò kan tí wọ́n lò níbi ayẹyẹ àjọ̀dún ti The Miseducation of Lauryn Hill..[5] Umuhire gba àmì-ẹ̀yẹ ti Villa Romana ní ọdún 2020.[3]
Wọ́n ti ṣe ìfihàn àwọn iṣẹ́ rẹ̀ níbi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ̀dún fíìmù tó fi mọ́ MOCA Los Angeles, MCA Chicago, Tribeca Film Festival, Smithsonian African American Film Festival àti International Film Festival Rotterdam.[4]
Àwọn àṣàyàn eré rè
àtúnṣe- 2015: Polyglot (Web series)
- 2016: Mugabo
- 2019: King Who
- 2020: Kana
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Agyen, Akua (9 May 2016). "TALKING FILM WITH DIRECTOR AND FILMMAKER AMELIA UMUHIRE". Ayiba Magazine. Archived from the original on 7 November 2021. https://web.archive.org/web/20211107000854/http://ayibamagazine.com/talking-film-director-filmmaker-amelia-umuhire/. Retrieved 14 October 2020.
- ↑ "Speaking from the Void: A Conversation with Filmmaker Amelia Umuhire". MCA. 13 December 2018. Retrieved 14 October 2020.
- ↑ 3.0 3.1 Negusse, Mearg (12 December 2019). "Amelia Umuhire: Unpacking Hidden Rwandese Stories". Contemporary And. https://www.contemporaryand.com/magazines/amelia-umuhire-unpacking-hidden-rwandese-stories/. Retrieved 14 October 2020.
- ↑ 4.0 4.1 "Amelia Umuhire: FKBP5". Contemporary And. 7 February 2019. https://www.contemporaryand.com/exhibition/amelia-umuhire-fkbp5/. Retrieved 14 October 2020.
- ↑ Price, Yasmina. "Amelia Umuhire, Polyglot Ep. 2: Le Mal du pays (Homesickness)". E-flux. Retrieved 14 October 2020.
Àwọn ìtakùn Ìjásóde
àtúnṣe- IFFR profile Archived 2021-11-05 at the Wayback Machine.