Anandi Gopal Joshi
Anandibai Gopalrao Joshi (tí wọ́n bí ní 31 March 1865 tó sì kú ní 26 February 1887) jẹ́ dọ́kítàbìnrin àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ India. Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tó wá láti Bombay presidency ti ìlú India láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ètò ìṣẹ̀gùn ti ìgbàlódé ní United States.[1] Orúkọ mìíràn tí wọ́n máa ń pè é ni Anandibai Joshi àti Anandi Gopal Joshi (níbi tí Gopal jẹ́ àgékúrú orúkọ ọkọ rẹ̀, ìyẹn Gopalrao.
Anandi Bai Joshi | |
---|---|
A portrait photo of Anandibai Joshi | |
Ọjọ́ìbí | Yamuna Joshi 31 Oṣù Kẹta 1865 Kalyan, Bombay Presidency, British India |
Aláìsí | 26 February 1887 Pune, Bombay Presidency, British India | (ọmọ ọdún 21)
Resting place | Poughkeepsie, New York, United States (ashes) |
Orúkọ míràn | Anandibai |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Woman's Medical College of Pennsylvania |
Olólùfẹ́ | Gopalrao Joshi |
Signature | |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeOrúkọ àbísọ rẹ̀ ni Yamuna, inú ìdílé Marathi Chitpavan Brahmin ni wọ́n sì bí Joshi sí. Gẹ́gẹ́ bí àṣà ìlú wọn, àwọn òbí rẹ̀ fún fọ́kọ nígbà tó wà ní ọmọdún mẹ́sàn-án. Gopalrao Joshi, tó jẹ́ opókùnrin, tó sì fi ogún ọdún jù ú lọ ni wọ́n fẹ́ ẹ fún.[2] Lẹ́yìn ìgbéyàwó rẹ̀, ọkọ rẹ̀ sọ orúkọ rẹ̀ di 'Anandi'.[3] Gopalrao Joshi ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé ní Kalyan. Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé e lọ Alibag, kí ó ṣẹ̀ tó wá lọ Kolhapoor (Kolhapur). Ó jẹ́ aláròjinlẹ̀ onítẹ̀síwájú, tí ó sì fọwọ́ sí kí obìnrin kàwé.[4]
Ní ọmọdún mẹ́rìnlá, Anandibai bímọ ọkùnrin, àmọ́ ọmọ náà lo ọjọ́ mẹ́wàá péré nítorí àìrítọ̀ọ́jú ìwòsàn tó péye. Èyí sì ló yí ayé Anandi padà, tó sì fún un ní ìwúrí láti di oníṣègùn.[5] Kò pé ní ọkọ rẹ̀ fi sí ilé-ẹ̀kọ́, kí wọ́n tó wá kó lọ Calcutta. Ibẹ̀ ló ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ èdè Sanskrit àti èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Venkatraman, Vijaysree (27 July 2014). "This woman in 1883 had the best answer to the question of why a girl would want to be a doctor". Qz.com. https://qz.com/240793/this-woman-in-1883-had-the-best-answer-to-the-question-of-why-a-girl-would-want-to-be-a-doctor/.
- ↑ "Who is Anandi Gopal Joshi?" (in en-US). The Indian Express. 31 March 2018. http://indianexpress.com/article/who-is/who-is-anandi-gopal-joshi-5117944/.
- ↑ "Anandibai Joshi". Streeshakti The Parallel Force. Streeshakti. Retrieved 23 March 2018.
- ↑ Rao, Mallika (8 April 2014). "Meet The Three Female Medical Students Who Destroyed Gender Norms A Century Ago" (in en-US). Huffington Post. https://www.huffingtonpost.com/2014/04/08/19th-century-women-medical-school_n_5093603.html.
- ↑ Falcone, Alissa (27 March 2017). "Remembering the Pioneering Women From One of Drexel's Legacy Medical Colleges" (in en). DrexelNow. http://drexel.edu/now/archive/2017/March/Women-Physicians/.