Angel Unigwe
Angel Unigwe (orúkọ àbísọ rẹ̀ ni Angel Onyinyechi Unigwe; tí a bí ní ọjọ́ kẹta-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 2005) jẹ́ òṣèré obìnrin ti ilẹ̀ Nàìjíríà, ó jẹ́ aláfiwé, àti aṣètò tí ó tún ṣe ìfihàn nínú àwọn ìkéde tẹlifísàn olókìkí.
Angel Unigwe | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Angel Onyinyechi Unigwe 27 Oṣù Kẹfà 2005 Lagos, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Iṣẹ́ | Actress, model, presenter |
Ìgbà iṣẹ́ | 2011 – present |
Iṣẹ́ Rẹ̀
àtúnṣeṢàfimọ̀ sí ilé-iṣẹ́ fíìmù nípasẹ̀ ìyá rẹ̀, Unigwe bẹ̀rẹ̀ bí òṣèré ọmọdé tí ó ṣe àfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọdún 2015 lẹ́hìn tí ó gba àwọn ipa ní 'Alison's Stand,' járá tẹlifísàn Nàìjíríà olókìkí; àti pé láti ìgbà náà ó ti tẹ̀síwájú láti mú ọkàn àwọn òǹwòrán fíìmù dùn'. [1] Akòròyìn Unigwe ni oníròyìn Nàìjíríà Obaji Akpet.
Àwọn Yíyàn Rẹ̀ Àti Àmì Ẹ̀yẹ
àtúnṣeUnigwe ti gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn yíyàn àti pé ó ti gba àwọn àmì ẹ̀yẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú Òṣèré Ọmọdé (Child Actor) ti Ọdún 2019 ní Ààmì Ẹ̀yẹ Intellects Giant; [1] Ó lọlé pẹ̀lú àmì ẹ̀yẹ Best Young/Promising Actor ní ọjọ́ kẹta-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 2019, ní ẹdá ọdún 2019 ti Africa Movie Academy Awards (AMAA) );[2] Òṣèré ọmọdé tí ó dára jùlọ nínú fíìmù kan ní àmì ẹ̀yẹ ọdún 2021 'Best of Nollywood ' (BON) fún ipa rẹ̀ nínú 'Strain'. [1]
Àwọn Ìtọ́ka Sí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 "Angel-Onyi wins child actor award". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 5 May 2019. Retrieved 7 November 2021.
- ↑ "Winners for di 2019 Africa Movie Academy Awards". BBC News Pidgin. https://www.bbc.com/pidgin/tori-50176271.