Angela Aquereburu (tí a bí ní 11 Oṣù kíní ọdún 1977) jẹ́ oǹkọ̀tàn, olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Tógò.

Angela Aquereburu
Ọjọ́ìbí11 Oṣù Kínní 1977 (1977-01-11) (ọmọ ọdún 47)
Orílẹ̀-èdèTogolese
Iṣẹ́Screenwriter, film producer, film director, TV host
Notable workHospital IT (2017)
Angela Aquereburu

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Aquereburu ni a bí ní Tógò sí ọwọ́ ìyá tí ó wá láti Guadeloupe, orílẹ̀-èdè Faransé. Ó ní ìfẹ́ sí eré ṣíṣe láti ìgbà èwe rẹ̀. Ó lọ ilé-ìwé ní Tógò àti Pointe-a-Pitre ní Guadeloupe, ṣááju kí. ó tó gbéra lọ sí ìlú Paris láti tún lọ kẹ́kọ̀ọ́ gíga ní ilé-ìwé ESCP Business School.[1] Ó gba oyè gíga nínu ìmọ̀ ìdáko òwò.[2] Aquereburu ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú òṣèrékùnrin Jean-Luc Rabatel. Ó ti ń ṣiṣẹ́ ìṣàkóso àwọn òṣìṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ṣùgbọ́n ní́ ọdún 2008, ní àkókò ìgbà tí ó fi wá fún ìsinmi ní orílẹ-èdè Tógò, ó ṣàkíyèsí pé ẹ̀yà eré tẹlifíṣọ̀nù kan ni wọ́n maa ń ṣe ní ìlú Tógò, òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ síì wòye sí ẹ̀yà míràn, èyí tí ó dá lóri ọ̀kadà wíwà.[3] Ní ọdún tí ó tẹ̀le, Aquereburu àti ọkọ rẹ̀ kó lọ sí ìlú Lomé láti máa gbé níbẹ̀, wọ́n sì dá ilé-iṣẹ́ Yobo Studios sílẹ̀.[4] Ẹ̀yà eré tẹlifíṣọ̀nù míràn tí wọ́n gbèrò jẹ́ ìpìlẹ̀ fún eré Zem tí Canal àti Afrique dì jọ ṣe olóòtú rẹ̀.[5]

Aquereburu tún ti ṣiṣẹ́ lóri eré Palabre.[2] Ní ọdún 2017, ó ṣe àgbékalẹ̀ ètò tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Hospital IT, èyítí ó dá ĺori líla àwọn èyàn lọ́yẹ̀ lóri àìsàn ibà àti àwọn àìsàn tó níṣe pẹ̀lú bíbóra. Ó jẹ́ kó di mímọ̀ wípè, oyún kejì òun ló fún òun ní ìwúrí láti ṣe àgbékalẹ̀ eré náà, àti pé eré Grey's Anatomy nípa pàtàkì lóri ṣíṣe eré náà.[5] Eré náà gbaa àmì-ẹ̀yẹ ti eré tẹlifíṣọ̀nù tí ó dára jùlọ níbi àjọ̀dún Vues d'Afrique tó wáyé ní ìlú Montreal.

Ní ọdún 2018, Aquereburu ṣe olóòtú fún ètò Les Maternelles d'Afrique, eré Áfíríkà kan tí ń ṣe ìbádọ́gba ẹ̀yà eré Faransé kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ La Maison des Maternelles. Ètò náà dá lóri wíwòye sí ọ̀rọ̀ ìlóbìnrin púpọ̀ láìṣojúùṣájú.[6]

Àkójọ àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • 2009 : Zem Season 1 (26x5min), co-director
  • 2012 : Palabres (26x5min), co-director
  • 2016 : Mi-Temps (40x3min), co-director
  • 2016 : Zem season 2 (50x3min), co-director
  • 2017 : Hospital IT (26x26min), co-director
  • 2017 : Zem season 3 (60x3min), co-director
  • 2018 : Les Maternelles d'Afrique Season 1 (20x26min), host
  • 2019 : Oasis Season 1 (20x26min), co-director
  • 2019 : Les Maternelles d'Afrique Season 2 (26x26min), host
  • 2020 : Les Maternelles d'Afrique Season 3 (26x26), host
  • 2023 : Web Series AHOE, producer[7]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Muya, Leslie (19 February 2018). "Angela Aquereburu, la Shonda Rhimes togolaise" (in French). Jeune Afrique. https://www.jeuneafrique.com/664246/culture/angela-aquereburu-la-shonda-rhimes-togolaise/. Retrieved 1 October 2020. 
  2. 2.0 2.1 Juraver, Senami (2 October 2017). "Angela Aquereburu, productrice de séries à succès" (in French). Forbes Afrique. Archived from the original on 13 November 2021. https://web.archive.org/web/20211113085318/https://forbesafrique.com/angela-aquereburu-productrice-de-series-a-succes/. Retrieved 1 October 2020. 
  3. Muya, Leslie (19 February 2018). "Angela Aquereburu, la Shonda Rhimes togolaise" (in French). Jeune Afrique. https://www.jeuneafrique.com/664246/culture/angela-aquereburu-la-shonda-rhimes-togolaise/. Retrieved 1 October 2020. 
  4. Constant, Raphaëlle (27 September 2019). "Angela Aquereburu, togolaise, productrice de séries télévisées en Afrique" (in French). Radio France internationale. http://www.rfi.fr/fr/emission/20190401-angela-aquereburu-togolaise-productrice-series-televisees-afrique. Retrieved 1 October 2020. 
  5. 5.0 5.1 Muya, Leslie (19 February 2018). "Angela Aquereburu, la Shonda Rhimes togolaise" (in French). Jeune Afrique. https://www.jeuneafrique.com/664246/culture/angela-aquereburu-la-shonda-rhimes-togolaise/. Retrieved 1 October 2020. 
  6. "Angela Aquereburu, une showrunneuse qui fait bouger les lignes". Elle Ivoirienne. 15 April 2018. Archived from the original on 15 April 2018. https://web.archive.org/web/20180415192117/https://www.elle.ci/Societe/Femmes-a-suivre/Angela-Aquereburu-une-showrunneuse-qui-fait-bouger-les-lignes. Retrieved 1 October 2020. 
  7. https://www.togofirst.com/fr/culture/3101-13357-cinema-angela-aquereburu-productrice-de-la-web-serie-ahoe-rencontre-le-premier-ministre-togolais

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe

Angela Aquereburu at the Internet Movie Database