Anna Böeseken
Anna Jacoba Böeseken | |
---|---|
Born | Pretoria, Transvaal Colony | 23 Oṣù Kẹ̀wá 1905
Died | 28 June 1997 Cape Town | (ọmọ ọdún 91)
Known for | Authority of history of the Dutch East India Company |
Anna Böeseken (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Anna Jacoba Böeseken, tí wọ́n bí sí ìlú Pretoria ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹwàá ọdún 1905; tí ó sì kú ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1997 sí Cape Town) fìgbà kan jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa, tó máa ń sọ̀tàn, tó tún jẹ́ oníròyìn àti òǹkọ̀wé, tí orúkọ iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ AJ.[1] Ó gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ nínú sísọ ìtàn Dutch East India Comany tó wà láàárín ọdún 1602 àti 1798.[2]
Ìgbésíayé rẹ̀
àtúnṣeÀwọn òbí Böeseken jẹ ọmọ ìlú Germany. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní South Africa àti Europw kí ogun àgbáyé kejì tó ṣẹlẹ̀.
Awọ́n ọ̀jọ̀gbọ́n òde-òní ṣàfihàn rẹ̀ gẹ́gé bí i ọ̀kan lára àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lórí ìtàn àti ìtànkálẹ̀ Dutch East India Company. Àtẹ̀jáde ti ọdún 2013, nínú jọ́nà Historia volume 48, Issue 2, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ “Historia – Dr. Anna Boëseken (1905-1997) : kenner van die Kaapse VOC-geskiedenis (Gẹẹsi: Amoye ti itan-akọọlẹ Cape VOC) "ṣe àyẹ̀wò àwọn àfikún rẹ̀ nínú ìṣẹ̀dálẹ̀ ìtàn VOC ní South Africa, àti ṣíṣe ògbúfò rẹ̀ fún àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti àwọn ènìyàn inú àwùjọ".[2]
Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹfà ọdún 1964, ó dá ẹgbẹ́ Genealogical Society sílè. Ẹgbẹ́ yìí sì máa ń ṣe àtẹ̀jáde jọ́nà Familia ní ẹ̀mẹẹrin lọ́dún.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Romero, Patricia (1998-08-31) (in en). Profiles in Diversity: Women in the New South Africa. MSU Press. p. 1900. ISBN 9780870139482. https://books.google.com/books?id=0TWBnVMQldUC&pg=PA1900.
- ↑ 2.0 2.1 Wet, Con De (2003-11-01) (in af). Dr. Anna Boëseken (1905-1997) : kenner van die Kaapse VOC-geskiedenis. https://journals.co.za/content/hist/48/2/EJC38127. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; name ":1" defined multiple times with different content - ↑ Breuer, Rosemarie. "Anna Jacoba Böeseken". www.stellenboschwriters.com. Retrieved 2017-11-29.