Apiiri

E.I. Oso

E.I. Ọ̀ṣọ́ (1979), ‘Àpíìrì’, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.

Eré àpíìrì jẹ́ ohun tí ó ní orin, ìlù àti ijó nínú. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí, erée pelebe ni ó di àpíìrì níwọ̀n ìrínwó ọdún sẹ́hìn. Ìjerò-Èkìtì ni eré àpíìrì yìí ti bẹ̀rẹ̀. Ìtàn fi yé wa pé wọn mọ̀ ọ́n fúnra wọn ni, kì í ṣe wí pé wọ́n mú un wá láti Ilé-Ifẹ̀ tí ó jẹ́ orírun Yorùbá. Eré yìí bẹ̀rẹ̀ ní àkókó tí àwọn ará Ìjerò mú Alákeji jọba dípò ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ó jẹ́ ọba. Ìtàn fi yé wa pé nígbà tí ogun àti ọ̀tẹ̀ yí ìlú Ìjerò ká, ẹ̀gbọ́n Alákeji tí ó jẹ́ ọba wá gbéra láti lọ wá ọ̀nà tí wọn yíò fi ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn ká. Nígbà tí àwọn ará ìlú kò tètè rí i, wọ́n gbèrò láti fi àbúrò rẹ̀ Alákeji jọba. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n Alájeji wá padà, ó rí i pé wọ́n ti mú àbúrò òun jọba. Ó ka gbogbo ètùtù tí wọ́n ní kí ará ìlú ṣe láti lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn káàkiri. Ìtàn yìí náà ni ó fi yé wa pé kò torí èyí bínú kúrò ní ìlú. Ó sọ fún àwọn ará ìlú pé kí wọn máa ṣe eégún fún òun lákòókò ọdún Ògún fún ìrántí òun, kí wọn sì máa ṣeré àpíìrì tí egúngún yìí bá jáde. Lẹ́hìn èyí ni eré àpíìrì ti bẹ́rẹ̀ ní ìlú Ìjerò-Èkìtì.

Àwọn alápìíìrì tí ó ti dolóògbèé ni Ọ̀gbẹ́ni Àṣàkẹ́ Ìwénifá, Ajórùbú, Àjàlá, Olóyè Ọsọ́lọ̀ Òkunlọlá, Afọlábí Ọ̀jẹ̀gẹ̀lé. Àwọn eléré àpíìrì tí ó tì ń ṣeré ní Ìjerò báyìí ni Èyéọwá Ọmọyẹyè, S.O. Fómilúsì tí ó sọ ìtàn bí eré àpíìrì ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Ìjerò-Èkìtì. Gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹnu bà á ní ọ̀rọ̀ àkọ́sọ, ìbágbé pọ̀ àwọn èèyàn ni ó mú eré àpíìrì tàn kálẹ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì.

Èèyàn méjọ sí mẹ́wàá ni ó sábà máa ń ṣeré àpíìrì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn mẹ́rin péré ni í máa ń lu ìlù. Ohùn méjì pàtàkì ni a ń bá pàdé nínú eré àpíìrì. Èkíní ni ohùn pàtàkì ni a ń bá pàdé nínú eré àpíìrì. Èkíní ni ohùn alámọ̀, tó sábà máa ń jáde lẹ́nu nígbà tí eléré àpíìrì bá fẹ́ salámọ̀. Èyìí fẹ́ jọ ohùn arò. Ohùn orin ni èkejì tí a máa ń bá pàdé nínú eré àpíìrì.

Lítíréṣọ̀ aláfohùnpè ni eré àpíìrì. Eré yìí sábà máa ń ní olórí tí yíò máa dá orin, tí àwọn yòókù yíò máa gbè ti ìlù bá ń lọ lọ́wọ́. Ẹni tí ń lé orin yìí lè ṣe ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tàbí ènìyàn méjì lápapọ̀ láti lè fi ohùn dárà nínú orin lílé. Nígbà míràn, ó lè ṣe ẹni tí ń dá orin náà ni yíò máa salámọ̀ láàrin eré, ó sì tún lè jẹ́ ènìyàn méjì yàtọ̀ sí àwọn tí ń dárin. Kíkọ́ ni mímọ̀ ni ọ̀rọ̀ eré yìí. Ẹni tí kò kọ́ ìlù eré àpíìrì tàbí orin rẹ̀ kò lè mọ̀ ọ́n. Àwọn eléré àpíìrì máa ń ronú láti lè mú kí wọn mú oríṣìíríṣìí ìrírí wọn lò nínú orin wọn. Èyí fi ìdàgbàsókè ti ń dé bá eré àpìírì hàn. Ní àtijọ́ ọdún Ògún ni eré àpíìrì wà fún, ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé yíyí ni ayé ń yi, àwọn òṣèré náà wá ń báyé yí nípa pé kí wọn ṣẹ̀dá orin àpíìrì fún onírúurú àṣeyẹ tí a ó mẹ́nu bà níwáju. Eré àpíìrì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ àti òye tí ó fi ọgbọ́n, ìrònú, àkíyèsí, èrò, èèwò àti ìgbàgbọ́ àwa Yorùbá hàn.

Àwọn ohun tí ó ya eré àpíìrì sọ́tọ̀ sí eré ìbílẹ̀ míràn ni, irúfẹ́ ìlù tí a ń lò fún eré yìí, ọ̀nà tí a ń gbà kọ orin àpíìrì àti bí ìlù tí a ń lò ṣe ń dún létí. Nǹkan mìíràn tí ó tún ya eré yìí sọ́tọ̀ sí òmíràn nip é agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì nìkan ni a ti ń ṣe irú eré yìí ní gbogbo ilẹ̀ káàárọ̀-oò-jíire.

Àwọn ohun tí a ń lò bí ìlù nínú eré àpíìrì láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá ni agbè tí ajé wà lára rẹ̀. Agbè àti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ jẹ́ ohun èlò ìlù lílù àti ijó jíjó tí a dá sílẹ̀ ní àkókò Ẹ́mpáyà Bìní. Àwọn Ẹ̀gùn àti Pópó ni ó dá a sílẹ̀ ní àkókò ọba Oníṣílè. Agogo náà tún jẹ́ ọ̀kan nínú ohun èlò eré àpíìrì. Àwọn agbè tàbí ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ̀nyí máa ń tóbi jura wọn, kí dídún wọn bàá lè yàtọ̀ síra. Orúkọ tí a ń pe ajé tàbí agbè wọ̀nyí ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì ni, Èyé ajé tàbí Èyé ùlù, kugú, ọ̀pẹẹẹrẹ àti agogo. Bí àwọn agbè wọ̀nyí ṣe tóbi sí ni a ṣe fún wọn lórúkọ. Wọn máa ń lo ìrùkẹ̀rẹ̀ láti jó ijó àpíìrì. Ìdàgbàsókè tí ń dé bá ohun èlò eré àpíìrì. Ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi hàn. Àwọn Yorùbá ló ń pà á lówe pé, ‘báyé bá ń yí ká báyé yí, bígbà bá ń yí ká bá ìgbà yí, ìgbà laṣọ, ìgbà lẹ̀wù, ìgbà sì ni òdèré ikókò nílè Ìlọrin.’ Nísìsíìyí, arábìnrin Adépèjì Afọlábí tí ó jẹ́ eléré àpíìrì ní Ìdó-Èkìtì ti mú ìlù Bẹ̀mbẹ́ àti àkúbà mọ́ agbè àti agogo tí a ń lò tẹ́lẹ̀ nínú eré àpíìrì.

Àwọn olùgbọ́ kó ipa pàtàkì nínú eré àpíìrì tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú Lítíréṣọ̀ aláfohùnpè. Àwọn olùgbọ́ máa ń gbe orin pẹ̀lú àwọn òṣèré. Wọn a máa jó, wọn a sì máa pa àtẹ́wọ́ tí erá bá ti wọ̀ wọ́n lára. Irú ìtẹ́wẹ́gbà báyìí sì máa ń mú kí ọ̀sèré túbọ̀ ṣe eré tí ó dára lójú agbo.

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí mo ṣe ṣáájú, ọ̀nà tí àwọn alápíììrì ń gbà ṣe eré wọn ni kí olórí eré máa lé orin fún àwọn elégbè tí yíò máa gbe orin tí ó bá dá. Olórí lè kọ́kọ́ kọrin kí alámọ̀ tẹ̀lé e tàbí kí ó kọ́kọ́ salámọ̀ kí ó tó kọrin. Kò sí bátànì kan pàtó tí alápìíìrì gbọ́dọ̀ tẹ̀lé nínú eré nítorí pé bí ó bá ṣe wuni ni a ṣe ń ṣèmọ̀le ẹni Ní àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí, alámọ̀ ni eléré àpíìrì yìí fi bẹ̀rẹ̀ erée rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wò ó.

Lílé (Alámọ̀) – Ò rì polóó ùdín ria

Ọ̀bà ǹ bá e mú, kán an síì

Mú un titun barun ùn

Láiún ùgbín rẹ̀ pẹgbẹ̀fà

An máiun rẹ̀ pegbèje lúléè mi,

Ọ karee o,

Mè í múléè ni,

Mẹ́ mọ̀ búyà kànkàn í rè