Arese Ugwu (tí wón bí ní March 19, 1986) jẹ́ Olùkọ̀wé àti olùṣe filmu ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ Arese sí Smart money Arese, orúkọ tí wọ́n fun nítorí filmu rẹ̀; Smart money woman àti ilé-isé rẹ̀; Smart Money Africa.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Arese sí inú ìdílé Victor àti Funke Ogiemwonyi ní ìlú Benin, ìpínlè Edo, Nàìjíríà.[2] O gba àmì ẹyẹ Bachelor's degree nínú ìmò ìsòwò nínú ilé ìwé ìsòwò Aston, àti àmì ẹyẹ master degree nínú ìmò Economics Development ní ilé ìwé college Yunifásitì ti London. Ó tún kàwé ní ilé ìwé ìsòwò ìpínlè Eko(Lagos business school) àti London business school.[3]

Isẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Nínú akitiyan rẹ̀ láti ran àwọn ọmọbìnrin lọ́wọ́ nínú ètò ìsúná wọn, Arese Ugwu dá Smart Money Africa sílè.[4] Ègbé náà jé ẹgbẹ́ tí ó ran àwọn ọmọbìnrin lọ́wọ́ láti kó nípa ètò ìsúná ní ọ̀nà tí ó rọrùn. Ète Arese ni láti yí ìtàn àìní ní Afrika padà nípa kíkó àwọn ènìyàn nípa ètò ìsúná. Arese ma ń lo orisirisi ìtàn láti fi kó àwọn ọmọ Afrika nípa ètò isuna,ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà sì ni ó ma ń lọ àwọn oríṣi itakun ayélujára. Arese tún ni oludasile Smart Money Travel

 Ní ọdún 2016, ó ko ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ 'The Smart Money Woman - an African girl journey to financial freedom'. Ní ọdún 2020 ṣe filmu kan lórí ìwé rẹ̀.[5]

Arese ma ń ṣẹ ètò kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Your life, Your money" lórí Guardian's TV.

Àwọn Ìtókasí

àtúnṣe
  1. "The Smart Money Woman (TV Series 2020– )". IMDb. November 30, 2020. Retrieved October 23, 2022. 
  2. "Arese Ugwu". Trybe City Wiki. January 7, 2022. Archived from the original on October 23, 2022. Retrieved October 23, 2022. 
  3. everipedia.org https://everipedia.org/wiki/lang_en/arese-ugwu. Retrieved October 23, 2022.  Missing or empty |title= (help)
  4. "Meet the Crew: Arese Ugwu". Smart Money Africa. October 21, 2021. Archived from the original on October 23, 2022. Retrieved October 23, 2022. 
  5. Okonkwo, Chukkie (July 30, 2021). "Netflix picks up Arese Ugwu's 'The Smart Money Woman' series". eelive. Retrieved October 23, 2022.