Arinola Olasumbo Sanya[1] (tí a bí ní ọdun 1953) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn àti Kọmíṣọ́nà fún ètò-ìlera ara ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Arinola di òjògbón ní ọdun 2000, èyí tí ó sọ di obìnrin àkọ́kọ́ láti di ọ̀jọ̀gbón nínú bí a ṣe ń dá isẹ́ ara bọ̀ sípò (physiotherapy) ní orílẹ̀ Afrika, àti obìnrin àkọ́kọ́ láti di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmò Physiotherapy ní Nàìjíríà. Ó wà lára àwọn Ẹni iyì ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.[2]

Arinola OlaSumbo Sunya
Fọ́tò Ọ̀jọ̀gbọ́n Arinola Olasunmbo Sanya tí wọ́n yà ní ọ́fícì rẹ̀ ní Yunifásitì ìlú Ibadan ní ọdun 2013
Ọjọ́ìbí1953
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Physiotherapist

Arinola ni igbá kejì adarí Yunifásítì ìlú Ìbàdàn.[3] Arinola bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ní Salvation Army Primary School ní Surulere ti Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó tẹ̀síwájú ní Queens College, Yaba, Ìpínlè Èkó níbi tí wọ́n ti fi joyè Head Girl. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmò Physiotherapy ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn.

Ìsìn ìjọba àtúnṣe

Arinola di Kọmíṣọ́nà fún ètò-ìlera ara ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdun 2005.[4]

Ìdílé àtúnṣe

Ọkọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Sanya ní Dr. Yemi Sanya, onímọ̀ ọ̀gùn òyìnbó àti oníṣòwò ní ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà. Wọ́n ní ọmọ mẹrin.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "CITATION OF PROFESSOR ARINOLA OLASUMBO SANYA | UNIVERSITY OF IBADAN". ui.edu.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2017-12-22. 
  2. "UI appoints new DVC, registrar — the Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper". Archived from the original on 2012-04-28. Retrieved 2012-05-12.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "CITATION OF PROFESSOR ARINOLA OLASUMBO SANYA | UNIVERSITY OF IBADAN". www.ui.edu.ng. Archived from the original on 2021-05-20. Retrieved 2021-05-20. 
  4. "Arinola Olasumbo Sanya". www.wikidata.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-05-20. 
  5. "Nigeria Physiotherapy Network - Arinola O. Sanya". www.nigeriaphysio.net. Retrieved 2022-08-10.