Arun HIV/AIDS ni Naijiria

Lásìkò 2014 ní Nàìjíríà, HIV wọ́pọ̀ láàrín àwọn ọ̀dọ́ tó ti bàlágà tó ti tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún sí ọ̀kandị́nláàdọ́ta[1] jẹ́ ìdá 3.17%.[2] Ilẹ̀ Nàìjíríà ni ó gbé ipò kejì nínú àwọn tí ó n semi pẹ̀lú àrùn HIV.[3] Àrùn HIV  di àjàkálẹ̀ tí ó sì pọ̀ ju ara wọn lọ ní agbègbè sí agbègbè. Làwọn ìpínlẹ̀ kan, ti tàn kálẹ̀ arun, ni o da lori iwa ati isemi ti o le koko, nigba ti awon itankale re ni awon ipinle miiran da lori ibalopo pelu opo eniyan.[citation needed] Àwọn ọ̀dọ́ langba àti àwọn àgbàlagbà ni wọ́n sì kó sí páńpẹ́ HIV., táwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ̀àti àwọn abilékọ ló wọ́pọ̀ jù àwọn ọkùnrin lọ.[4]  Ọ̀pọ̀ ìwà ló lè ṣokùnfà ìtànkálẹ̀ àrùn náà, lára àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ni: Iṣẹ́ aṣẹ́wó, èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrín olówò ìbálòpọ̀, tí ó sì ti ṣokùnfa ìtànká àrùn tí à ń kó níbi ìbálòpò, ìwà ìbálòpọ̀ Akọ sí Akọ àti ìwà ìbálòpọ̀ ọlọ́pọ̀ èrò, àti ìwà fífi àwọn ọmọbìnrin sòwò ẹrú lọ sílẹ̀ òkèrè, ìwà àìṣàmójútó àyèwò ẹ̀jẹ̀ kí a tó gbàá tàbí fúni.[5]

Prevalence of AIDS in Nigeria from 1991–2010. Includes predictions up to 2016.

Ilẹ̀ Nàìjíríà láti àsìkò ìṣèjọba ológun (Ìṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà) tí ó gba orílẹ̀ èdè náà kan fún odidi ọdún méjì-dínlógún lára ọdún mẹ́tàdín-lọ́gọ́fà tí orílè èdè Nàìjíríà ti gba òmìnira (Ìgba Òṣèlú Àkọ́kọ́ Nàìjíríà) ní ọdún 1960. Òfin tí ó de ìbàjẹ́ àwùjọ kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó. Àwùjọ àwa ara wa kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ lásìkò ìsèjọba àwọn ológun ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òǹkà ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà nígbà náà nira láti mọ̀ pàá pàá nígbà akitiyan àti ṣe ìjọba àwa arawa láti lè fesè iṣé ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà múlẹ̀ (Ìṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà) kó ìpalára bá ìṣe déédé nípa ètò ìléra káàkiri àwọn agbègbè orílẹ èdè náà. Ìṣakóso àwọn alàkalẹ̀ ètò lẹ́sẹẹsẹ láti orí ìjọba àpapọ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀ mú ìsoro wa lọ́pọ̀lọpọ̀. Àwọn iléesé ètò ìlera tí ó jẹ́ ti aládani ni kò rí àmójútó dára dára, pàápàá jùlọ ni kò ní ìbáṣepọ pẹ̀lú iléesé ètò ìléra tí ìjọba níbi ti ẹ̀kọ́ nípa àrùn HIV àti ìmójútó àwọn ènìyàn ti kéré jọjọ. Ìtọ́jú àti ìrànlọ́wọ́ kò tó ǹkan láti ọwọ́ àwọn Dọ́kítà àti Nọ́ọ̀sì, nítorí iṣẹ́ ti pọ̀ jù wọ́n lọ àti wípé wọn kò ní ìmọ̀ àti ẹ̀kọ́ tó péye láti pèsè ètò ìléra tó yanrantí fún àwọn aláìsàn náà.[5][citation needed]

E tun le wo

àtúnṣe
  • Àjàkálè̩ àrùn AIDS
  • Ètò ìléra ni Naijiria
  • HIV/AIDS ni Afrika

Awon itoka si

àtúnṣe
  1. "Definitions and notes" Archived 2018-08-23 at the Wayback Machine. Accessed May 11, 2016.
  2. "HIV/AIDS - adult prevalence rate" Archived 2014-12-21 at the Wayback Machine. CIA World Factbook (2014) Accessed May 11, 2016.
  3. "HIV/AIDS - People Living with HIV/AIDS" Archived 2018-07-23 at the Wayback Machine. CIA World Factbook (2014) Accessed May 11, 2016.
  4. citation needed
  5. 5.0 5.1 "2008 Country Profile: Nigeria". U.S. Department of State. 2008. Archived from the original on 16 August 2008. Retrieved 25 August 2008.