Aso Radio (93.5 FM) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò ilẹ̀ Nàìjíríà, tó fìdí kalẹ̀ sí Abuja. Ìjọpa àpapọ̀ ló sì ń darí rẹ̀, ìyẹn Federal Capital Territory. Wọ́n dá ilé-iṣẹ́ rédíò yìí sílẹ̀ ní ọdún 1997, ẹni tó ṣagbátẹrù rẹ̀ ni Rtd. Brigadier eneral Jeremiah Timbut Useni, tó fìgbà kan jẹ́ mínísítà Abuja, nígbà náà. Studio àti ẹ̀rọ ìgbéròyìn-sáfẹ́fẹ́ wà ní orí-òkè Katampe, pẹ̀lú àtúngbéjáde rẹ̀ ní Karshi, Abaji, àti Bwari.[1]

Ní ọjọ́ 19, oṣù karùn-ún, ọdún 1999, Rtd. General Mamman T. Kontagora, tó jẹ́ mínísítà Federal Capital Territory fi àṣẹ sílẹ̀ láti ṣí ilé-iṣẹ́ ìgbéròyìn-sáfẹ́fẹ́ náà, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu. Wọ́n kéde ìkànni ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán kan, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Aso TV ní ọdún 2008, àmọ́ kò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ títí wọ ọdún 2012.[2]

Lákòókò tí ilé-iṣẹ́ náà jẹ́ ti ìjọba, Aso TV máa ń rówó látàri ìpolówó.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe