Australian
Austrolian ni a orúkọ fún ẹgbẹ́ àwọn èdè kan tí àwọn aborigine ń sọ. Àwọn èdè yìí fi bí obọ̀n lé ní igba (230) síbè àwọn tí ó ń sọ wọ́n kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n lọ. Wọ́n pín àwọn èdè wọ̀nyí sí ẹbí bí ọgbọ̀n ó dún méjì nítorí wí pé wọ́n ní wọ́n bá ara wọn tan. Gbogbo àwọn èdè wọ̀nyí, yàtọ̀ sí ọ̀kan nínú wọn ni ó wà ní àríwá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Australia àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá (Northern Territory) àti Queensland. Gbogbo ilẹ̀ tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kò ju ìdá mẹ́jọ ilẹ̀ Austrolia lọ. Ṣùgbọ́n èdè tí a ń pe ẹbí rẹ̀ ní Pama-Nyunga ni ó gba gbogbo ilẹ̀ yòókú ní Austrolia. Àwọn èdè tí ó wà nínú ebí yìí tó àádọ́ta tí àwọn ènìyàn sì ń lò wọ́n dáadáa. Àwọn èdè tí àwọn ènìyàn ń sọ jù ni twi, Wapiri, Aranda, Mabuyng àti Western Desert. Àwọn tí ó ń sọ òkọ̀ọ̀kan wọn lé tàbí kí ó dún díẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún. Láti nǹkan búséńtúrì kejìdúnlógún àwọn èdè tí ó ní àwọn tí ó ń sọ wọ́n ti ń dínkù jọjọ. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó sẹ́kì yìí ti ń parẹ́. Kò sí ẹni tí ó lè sọ bí ọjọ́ iwájú àwọn èdè aborigine yìí yóò ṣe rí ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ti ń ṣiṣẹ́ gidigidi lórí wọn báyìí láti nǹkan bí ọdún 1960 tí àwọn kan ti dìde láti jà fún fífún gbogbo ènìyàn ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin. Púpọ̀ nínú àwọn èdè wọ̀nyí ni ó ti ń ní àkọsílẹ̀ tí wọ́n fi àkọtọ́ Rómáànù (Roman alphabet) kọ. Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ sì ti ń lo èdè méjì., èdè mìíràn àti èdè mìíràn.