Ayẹyẹ ọdún àṣà ilẹ̀ Áfíríkà ti St. Louis

Ayẹyẹ ọdún àṣà ilẹ̀ Áfíríkà ti St. Louis (èyí tí a tún mọ̀ sí STLAAF tàbí St. Louis African Arts Fair) ó jẹ́ ayẹyẹ àṣà tí wọ́n máa ń ṣe ní ọdọọdún ní St. Louis, Missouri, èyí tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1991. Ayẹyẹ ọdún STLAAF jẹ́ ayẹyẹ ọlọ́jọ́ mẹ́ta èyí tí ó borí ayẹyẹ ọ̀sẹ̀ ìṣèrántí. [1][2] Ayẹyẹ ọdún àṣà ilẹ̀ Áfíríkà yìí jẹ́ èyí tí àwọn àjọ St. Louis African Heritage Association, Inc jẹ́ onígbọ̀wọ́ fún. Wọ́n dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ ní ọdún1995 tí ó sì jẹ́ ìyá ẹgbẹ́ fún STLAAF, ó sì jẹ́ ẹgbẹ́ tí kìí ṣe fún èrè jíjẹ. [1]

Ayẹyẹ ọdún yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1991 gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀ka iṣẹ́ ọnà àti àṣà ti African Studies Association níbi àpérò ọlọ́dọọdún ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlélọ́gbọ̀n irú ẹ̀ [3] èyí tí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Washington tí ó wà ní St. Louis gbé kalẹ̀. Onírúurú ayẹyẹ ni ó sì wáyé níbè.

Olú ilé ẹgbẹ́ àjọ yìí wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Washington University èyí tí ó wà ní St. Louis. Cynthia L. Cosby, Alákóso àwọn iṣẹ́ àkànṣe àti olùdarí fún àwọn ìgbìmọ̀ Black Alumni Council fún ilé ẹ̀kọ́ gíga Washington University ní St. Louis, [4] ni olùdásílẹ́ ayẹyẹ ọdún náà.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Best Festival - 2010, St. Louis African Arts Festival <http://www.riverfronttimes.com/bestof/2010/award/best-festival-1101992/>
  2. St. Louis African Arts Festival, Program Description (official website) <http://stlafricanartsfest.com/index.html>
  3. African Studies Association, Rutger's University (official website) <http://www.africanstudies.org/>
  4. Black Alumni Council, Washington University in St. Louis <http://bac.wustl.edu/>


Àdàkọ:US-festival-stub Àdàkọ:StLouis-stub