Ayo Adesanya
Ayọ́ Adésànyà (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ ọdún 1969) jẹ́ àgbà òṣèrébìnrin, olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì.[1][2] [3] Ó tún jẹ́ adarí àti olóòtú eré.[4][5] Ayo Adesanya máa ń ṣàfihàn nínuụ eré Yorùbá àti ti Gẹ̀ẹ́sì.
Ayo Adesanya | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 11 Oṣù Kẹjọ 1969 Ogun State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1986–present |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeIjagu, ní ìlú Ijebu, ní Ipinle Ogun ni Ayo Adesanya ti wá, ìyẹn ní apá Gúúsù ti apá ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè Naijiria. Ilé-ìwè St. Anne's ní ìlú Ibadan ni ó ti kàwé, fún ti alákọ̀ọ́bèrẹ̀ àti ti girama. Lẹ́yìn náà, ó lọ University of Ibadan láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Mass Communication.[6]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeAyo Adesanya bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní ọdún 1986 lẹ́yìn tí ó sin orílẹ̀-èdè rẹ̀ tán, ìyẹn NYSC. Ní ọdún 1996, ó darapọ̀ mọ́ àwọn tí ń ṣe eré àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè Naijiria. Fíìmù Tunji Bamishigbin tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Palace ní wọ́n ti kọ́kọ́ se àfihàn rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́.[7] Ó padà darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn tí ń ṣe fíìmù Yorùbá. Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní darí eré, tó sì ń gbé eré jáde. Ó ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré jáde, ó sì ti darí eré púpọ̀.[8] Ayo Adesanya tún máa ń ṣe fíìmù Yorùbá àti ti Gẹ̀ẹ́sì.[9]
Ayé rẹ̀
àtúnṣeAyo Adesanya fìgbà kan jẹ́ ìyàwó Goriola Hassan, àmọ́ wọ́n ò fẹ́ ara wọn mọ́ báyìí. Ó bí ọmọkùnrin kan.[10]
Díẹ̀ lára àwọn fíìmù rẹ̀
àtúnṣe- Remember Your Mother (2000)
- Dancer 2 ( 2001)
- Tears in My Heart 2 (2006)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Ayo Adesanya Finds Love Again". THISDAY LIVE. Archived from the original on 24 February 2015. Retrieved 24 February 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Ruth Olurounbi. "I would have married Ayo Adesanya - Pasuma". tribune.com.ng. Archived from the original on 24 February 2015. Retrieved 24 February 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Chioma, Ella (2021-04-04). "Actress Ayo Adesanya opens up on dating men in Yoruba movie industry". Kemi Filani News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-15.
- ↑ "Ayo Adesanya Finds Love Again". THISDAY LIVE. Archived from the original on 24 February 2015. Retrieved 24 February 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Ruth Olurounbi. "I would have married Ayo Adesanya - Pasuma". tribune.com.ng. Archived from the original on 24 February 2015. Retrieved 24 February 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "My eyes are blessings from God - Ayo Adesanya - Vanguard News". Vanguard News. Retrieved 24 February 2015.
- ↑ "I was never married to Goriola Hassan –Ayo Adesanya". The Punch. Archived from the original on 28 February 2015. Retrieved 24 February 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Simplicity gives my life balance –Ayo Adesanya". The Punch. Archived from the original on 28 February 2015. Retrieved 24 February 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "I can never go back to my ex-husband –Ayo Adesanya, actress". The Sun (Nigeria). 10 June 2016. Retrieved 15 September 2016.
- ↑ Latestnigeriannews. "My ex-husband and I were never legally married Ayo Adesanya". Latest Nigerian News. Retrieved 24 February 2015.