Ayoka Olufunmilayo Adebambo

Ayoka Olufunmilayo Adebambo jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Òjògbón nínú títún àwọn àbùdá ẹranko ṣe àti ìmọ̀ Ìṣiṣẹ́àbínimọ́.[1] Òun ni ọ̀jọ̀gbọ́n obìnrin àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ títún àbùdá ẹranko ṣe àti nínú ìmò ìsisẹ́àbínimọ́.[2][3] Ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2010, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Fellow of the Animal Science Association of Nigeria (ASAN).[4]

Ayoka Olufunmilayo Adebambo
Ọjọ́ìbíLagos, Nigeria
Orílẹ̀-èdèọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ẹ̀kọ́Yunifásítì ìlú Ibadan
Iṣẹ́Academics
EmployerFederal University of Agriculture Abeokuta, Nigeria
Gbajúmọ̀ fúnFirst female Professor of Animal Breeding and Genetics in Nigeria
TitleProfessor

Isẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Iṣẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n Ayoka bẹ̀rẹ̀ ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn níbi tí ó ń ti ń fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ kọ̀kan hàn kí ó tó lọ sí Institute of Agricultural Research and Training ní Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀. Nígbà tí ó wà ní Ilé-Ifẹ̀, ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ akitiyan nínú títún àbùdá àwọn elédè ṣe láti mú èrè wá ní títà wọn. Ní ọdún 1993, ó lọ sí ẹ̀ka ìmọ̀ títún àbùdá ẹranko ṣe ní Federal University of Agriculture, ti Abeokuta, Nàìjíríà. Ó wà lára àwọn adárí ilé-ìwé náà.[1]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "Professor Olufunmilayo Ayoka Adebambo". AnGR NIGERIA (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-04-10. Retrieved 2021-04-10. 
  2. Nigeria, Media (2018-03-19). "List Of Nigerian First Male & Female Professors In Various Disciplines". Media Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-04-10. Retrieved 2021-04-10. 
  3. EduCeleb (2017-10-04). "List of Pioneer Professors in Nigeria". EduCeleb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-04-10. 
  4. "Awards and Honours – Animal Science Association of Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-04-10. Retrieved 2021-04-10.