Bíọ́dún Ọ̀kẹ́owó
Bíọ́dún Ọ̀kẹ́owó tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Ọmọ Butty ni wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1971 (26th December 1971) [1] jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí Rẹ́mọ ni ìpínlẹ̀ Ògùn, ṣùgbọ́n ó dàgbà sí ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
àtúnṣeGẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, Bíọ́dún jẹ́ ọmọ bíbí Rẹ́mọ ni ìpínlẹ̀ Ògùn, ṣùgbọ́n Fádèyí ní ìpínlẹ̀ Èkó lo gbé dàgbà. Ó kẹ́kọ̀ọ́ àkóbẹ̀rẹ̀ ni ìpínlẹ̀ Èkó, ó kàwé gbàwé ẹ̀rí dìgírì àkọ́kọ́ (First Degree) nínú ìmọ̀ èdè ìjìnlẹ̀ Yorùbá àti ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ (Yorùbá and Communication Arts) ní Ifáfitì ìpínlẹ̀ Èkó (Lagos State University).[2] [3]
Aáyan rẹ̀ gẹ́gẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò
àtúnṣeBíọ́dún Ọ̀kẹ́owó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 2006 nígbà tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Ẹníyẹmí", ṣùgbọ́n nínú "Tọ́lání Ọ̀ṣìnìnrín", ni sinimá àgbéléwò tí ìràwọ̀ rẹ̀ ti tàn. "Ọmọ Butty" ni sinimá àgbéléwò àkọ́kọ́ tí Bíọ́dún Ọ̀kẹ́owó gbé jáde fún ara rẹ̀. Sinimá yìí ni ó ti gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, "Ọmọ Butty". Lọ́dún 2010, ilé iṣẹ́ Global Excellence fún ní àmìn ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò tó dára jù. Àìmọye àmìn ẹ̀yẹ ló ti gbà láti àkókò tí ó dara pọ̀ mọ́ àwọn eléré tíátà. [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Biodun Okeowo Biography - Age, Husband, Movies, & Pictures". 360dopes. 2018-11-05. Retrieved 2020-01-22.
- ↑ [/biodun-okeowo-biography-profile-wikipedia-fabwoman/ "Biodun Okeowo Biography - Profile - Wikipedia"] Check
|url=
value (help). FabWoman | News, Style, Living Content For The Nigerian Woman. 2019-12-26. Retrieved 2020-01-22. - ↑ 3.0 3.1 Adeyeri, Aderonke (2014-08-22). "My first sex experience - Biodun Okeowo - Vanguard News". Vanguard News. Retrieved 2020-01-22.