Baṣọ̀run Gáà
Baṣọ̀run Gáà jẹ́ ìwé ìtàn eré-oníṣe tí gbajúmọ̀ oǹkọ̀wé nì, Adébáyọ̀ Fàlétí kọ. Ó dá lórí ìtàn olóyè Baṣọ̀run tí ìlú Ọ̀yọ́ tí wọ́n ń pè ní Baṣọ̀run Gáà. Ó jẹ́ afọbajẹ ní ìlú Ọ̀yọ́ láyé àtijó. Kókó inú ìwé ìtàn eré oníṣe yìí ni wípé kí a má ṣe ìkà. Ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ni ònkọ̀wé náà fi kọ ìwé náà, tí ó sì gbé ìtàn rẹ̀ lé orí ìtàn gidi tí ó sì jẹ́ ojúlówó ìtàn ilé Yorùbá.
ìtàn Igbesiaye Baṣọ̀run Gáà
àtúnṣeGẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan ni BBC, ìtàn fi ye wa pe, Basọrun Gaa ni olori igbimọ Ọyọmesi, eyi to dabi Olootu ijọba laye ode oni, lẹyin Alaafin, tii se oriade ilu Ọyọ́, Basọrun Gaa lo tun ku. Ko si sẹni to le e sọ pe ti Basọrun Gaa ko jẹ eeyan gidi, wọn yoo fi jẹ oye Basọrun, to jẹ olori igbimọ lọbalọba fun Alaafin, tii se Ọyọmesi. Ni bayii, o wa yẹ ka mọ itan igbe aye akọni yii ati ipa to ko ni ilu rẹ, boya rere ni abi buburu. Basọrun Gaa ni olori ogun Ọyọ ile ati gbajumọ ilu ni saa onka ẹgbẹrun ọdun kẹtadinlogun si ikejidnlogun, 17th/18th century Basọrun Gaa se gudugudu meje ati ya a ya mẹfa lati rii daju pe Ọyọ ile akọkọ di ilu nla, o lagbara, to si fẹ de ọpọ ilu ati orilẹ-ede lode oni Lọdun 1750 ni Alaafin Labisi yan Gaa gẹgẹ bii Basọrun, olootu ijọba ati olori igbimọ lọbalọba ẹlẹni meje fun Alaafin nilu Ọyọ ile, ti agbara si n pa Gaa bi ọti Ilu Ọyọ ile roju, o tuba, o tusẹ lasiko ti Basọrun Gaa joye, ti Ọyọ si maa n gba isakọlẹ lati ọpọ ilu àmọ́nà to wa labẹ rẹ Tọmọde-tagba nilu Ọyọ lo n bẹru, ti wọn si n bọwọ fun Basọrun Gaa, tori pe o ni oogun abẹnu gọngọ, ti asẹ rẹ si mulẹ ni aarin ilu ju Alaafin Labisi to yan an sipo lọ Itan sọ pe Basọrun Gaa ni oogun pupọ, to si maa n parada di ẹranko to ba wu u, to fi mọ Ẹkun, Kiniun, Igala, Ọya ati bẹẹ bẹẹ lọ Ni kete ti Gaa di Basọrun ni Ọyọ ile lo pa meji ninu awọn ọrẹ imulẹ Alaafin Labisi, eyi to dun ọba naa de egungun, to si gba ẹmi ara rẹ lọdun 1750 naa Alaafin Awọnbioju lo jẹ Alaafin lẹyin Labisi, sugbọn niwọn igba toun naa kọ lati gba itọni lọdọ Basọrun Gaa, aadoje ọjọ pere lo lo lori itẹ ti Gaa fi ni ki wọn yẹju rẹ Alaafin Agboluaje to jẹ lẹyin Awọnbioju tiẹ ri ijọba se n tiẹ, tori o n gbọrọ si Basọrun Gaa lẹnu, sugbọn ọwọ Basọrun Gaa naa ni ẹmi rẹ papa bọ si Alaafin Majẹogbe tiẹ lo dun kan soso pere lori itẹ, ki Basọrun Gaa to ran sọrun ọsan gangan Lọdun 1774 ni Alaafin Abiọdun gori itẹ, to si n wọna bi yoo se rẹyin Basọrun Gaa, ko lee roju se aye, sugbọn Gaa pa ọmọbinrin Alaafin Abiọdun, Agbọrin, nigba to nilo ẹranko Agbọnrin, to si ni orukọ wọn jọra Ọrọ naa dun Abiọdun to bẹẹ, to si beere fun atilẹyin Onikoyi, ati aarẹ Ọna Kakanfo to jẹ nigba naa, Ọyalabi lati ilu Ajasẹ ipo, ki wọn lee tete rẹyin Basọrun Gaa Alaafin Abọdun kọkọ yọ ibẹru Gaa kuro lọkan awọn araalu, to si jẹ ki ibinu rẹ maa ru jade ni inu wọn, titi ti Basọrun Gaa fi rọ lapa, rọ lẹsẹ Lọdun 1774, ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan Ọyọ ile ya bo agboole Basọrun Gaa, ti wọn si wọ ọ lọ si ọja Akẹsan, ki wọn to sun un nina gburugburu, bẹẹ ni wọn pa a tọmọtọmọ, wọn jẹ ile Gaa run patapata Sugbọn ori ko akọbi rẹ, Ojo Aburumaku yọ ninu wahala yii, to si sa lọ si ilẹ Ibariba, eyi to fopin si aye fami lete ki n tutọ ti Basọrun Gaa ati idile rẹ n jẹ Idi ree ti awọn eeyan se maa n pa asamọ pe ‘Bo laya ko sika, to ba ri iku Gaa, ko sootọ’ Sugbọn iku Basọrun Gaa se akoba nla fun ijọba Ọyọ akọkọ, tori lẹyin iku Gaa ni ẹdinku ba bi awọn ọmọ ogun rẹ ti dangajia si ati agbara ilu naa, tawọn ilu kan si n sa kuro labẹ rẹ, titi ti Ọyọ ile akọkọ fi tu lọdun 1836.[1]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Baṣọ̀run Gáà: Ó yan ọba mẹ́rin, tó sì pa ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àmọ́ ọba karùn-ún ló pa á". BBC News Yorùbá (in Èdè Latini). 2019-10-21. Retrieved 2019-12-30.
- Adebayo Faleti (1972), Basorun Gaa. Ibadan, Nigeria: Onibon-oje Press and Book Industries (Nig) Ltd. Oju-iwe = 149.