Babatunde Omidina

Òṣéré orí ìtàgé

Babatunde Omidina tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́

Babatunde Omidina
Ọjọ́ìbí(1958-08-22)22 Oṣù Kẹjọ 1958
Lagos Island
Aláìsíoṣù Belu (Nòfẹ́mbà) ọdún un 2021
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànBaba Suwe
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
  • Actor
  • comedian
Ìgbà iṣẹ́1972- 2021
Notable workAṣọ Ìbora

Bàba Sùwé (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹjọ ọdún 1958 jẹ́ gbajúgbajà òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ òṣèré aláwàdà, ipa àwàdà ni ó sìn máa ń kó nínú sinimá tàbí eré orí ìtàgé tí ó bá ti kópa. Eré orí ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Ẹ̀rín Kèékèé" ni ìràwọ̀ rẹ̀ tí bú jáde, nínú eré yìí ni orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ yìí tí jẹyọ. [1] [2] Ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Belu (Nòfẹ́mbà) ọdún un 2021 ni Bàbá Sùwé dágbére fáyé. [3] [4]


Aáyan rẹ̀ nínú iṣẹ́ tíátà

àtúnṣe

Babatunde Omidina bẹ̀rẹ̀ eré tíátà lọ́dún 1971. O di ìlúmọ̀ọ́kà nínú eré orí ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Ẹ̀rín Kèékèé". Kódà, nínú eré aláwàdà yìí ni ó ti gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Bàba Sùwé. Lẹ́yìn èyí, ìràwọ̀ rẹ̀ tún búyọ sì í nígbà tí ó kópa nínú àwọn sinimá-àgbéléwò lóríṣiríṣi.[5]

Ààtò díẹ̀ lára àwọn sinimá àgbéléwò tí ó ti kópa

àtúnṣe
  • Bá ò kú
  • Ojú Olójú
  • Bàbá Londoner
  • Kò tán sí bẹ̀
  • Aṣọ Ìbora
  • Ọ̀bẹ̀ lọmọ
  • elébòlò""

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Your favorite newspapers and magazines.". PressReader.com. 2018-09-09. Retrieved 2019-12-12. 
  2. "Movie on my NDLEA ordeal, Oya’gbe ti, will be out soon – Baba Suwe". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2019-12-12. 
  3. "Baba Suwe dies". Guardian Newspapers. 2021-11-22. Archived from the original on 2021-11-23. Retrieved 2021-11-24. 

    Ìgbà èwe rẹ̀

    àtúnṣe

    Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, wọ́n bí Bàba Sùwé ní Ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹjọ ọdún 1958 ní Ìnàbẹ̀rẹ̀ ní erékùṣù ìlú Èkó (Lagos Island), ṣùgbọ́n ọmọ bíbí ìlú Ìkòròdú ni, ní ìpínlẹ̀ Èkó bákan náà. Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ni ile-ìwé Jamaitul Islamial Primary School ní ìlú Èkó. Ó tún kàwé nígbà èwe rẹ̀ ní Children Boarding School, Osogbo,ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kí ó tó tẹ̀ síwájú ní Adékànḿbí Commercial High School ní Mile 12, nílùú Èkó, bákan náà ó lọ sí Ìfẹ́olúwa Grammar School ni ìlú Òṣogbo, Olú-ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ibẹ̀ ní ó ti kàwé gba ìwé-ẹ̀rí ìwé-mẹ́wàá. Ọ̀rọ̀ Aláwàdà Bàba Sùwé kọjá "Àjànàkú kọjá mo rí nǹkan fìrí, bá a bá rérin, ká gbà ń pé a rérin, gbajúmọ̀ ni lágbo tíátà.<ref name="360dopes 2018">"Who is Baba Suwe? - Babatunde Omidina Biography - Age". 360dopes. 2018-07-27. Retrieved 2019-12-12. 

  4. "Help, my health is deteriorating, Baba Suwe cries out". Premium Times Nigeria. 2019-02-20. Retrieved 2019-12-12. 
  5. "Baba Suwe Returns To Nigeria From Medical Treatment Abroad". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2019-05-29. Retrieved 2019-12-12.