Bala Miller (1928–2003)[1] jẹ́ olórin ọmọ Nàìjíríà tó gbajúmọ̀ nípa kíkọ orin highlife ní Nàìjíríà.

Ayé rẹ̀

àtúnṣe

Òun ni ọmọ Rev Miller ti ìlú Zaria, tó jẹ́ missionary tí ó sì wá̀ lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Hausa tó gba ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́ẹ̀nì.[2] Wọ́n bí Miller ní ọdún 1928 ní ìlú Pankshin, ìpínlẹ̀ Plateau. Òun ní àbígbẹ̀yìn nínú àwọn ọmọbìnrin márùn-ún àti ọmọkùnrin mẹ́ta tí àwọn òbí rẹ̀ bí. Láti ìgbà èwe rẹ̀ ní ó ti mọ ohun tí orin ń jẹ́. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní nífẹ̀ẹ́ orin kíkọ́ nígbà tí wọ́n gbé bàbá rẹ̀ lọ sí Holy Trinity Church ní Lokoja, èyí sì mu kí ó ri oríṣiríṣi ohun èlò orin fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ilé-ìjọsìn yìí.[2] Miller bẹ̀r̀ẹ sí ni fi àwọn irinṣẹ́ yìí kọ́ bí wọ́n ti ń lò ó nínú orin kíkọ́ nígbà tí ó wà ní ọmọdún mésan. Bákan náà ni ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn olórin ní ilé-ìwé rẹ̀.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Babadoko, Sani. "H-Net Discussion Networks - OBIT: Bala Miller, Nigerian Musician". h-net.msu.edu. 
  2. 2.0 2.1 Oti, Sonny (2009). Highlife music in West Africa : down memory lane--. Lagos, Nigeria: Malthouse Press. pp. 65–75. ISBN 9789788422082.