Basketmouth
Bright Okpocha (tí a bí ni ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹ́sàn-án ọdún 1978 ní Ìpínlẹ̀ Èkó), tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Basketmouth tí gbogbo ènìyàn mò sí, jẹ́ apanilẹ́rìín àti òṣèré ọmọ Nàìjíríà. Ó ti ṣètò àwọn eré orin àwàdà ìmurasílẹ̀ olókìkí bíi "Basketmouth Uncensored" káàkiri àgbáyé.
Basketmouth | |
---|---|
Basketmouth at AMVCA 2020 | |
Orúkọ àbísọ | Bright Okpocha |
Ìbí | 14 Oṣù Kẹ̀sán 1978 Lagos State, Nigeria |
Medium |
|
Ajẹ́ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Years active | 2000–present |
Genres | |
Subject(s) | |
Ibiìtakùn | basketmouth.tv |
Basketmouth ti gbàlejò ìpeníjà àwàdà kan lórí Instagram, tí a pè ní "TwoThingsChallenge" èyí tí ó fa ariwo láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́, lẹ́hìn ìgbàtí ọ̀dọ kan ti fi fídíò kan hàn tí ó sọ àwọn nǹkan àìfọkànbalẹ̀ tí ó jọmọ́ ìbálòpọ̀, pẹ̀lú ọmọ kan ní wíwò ìsúnmọ́ nínú fídíò náà.[1]
Ó jẹ́ olùpìlèsè ti "Ghana Jollof".[2]
Ìtàn Ìgbésí Ayé Rẹ̀
àtúnṣeÌbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀
àtúnṣeÌpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n bí Bright Okpocha ṣùgbón ó wá láti ìpínlẹ̀ Abia ní Nàìjíríà. Ó parí ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ ti girama ní Apapa, Ìpínlẹ̀ Èkó, ó sì lọ sí Fásítì ti Benin, Ìpínlẹ̀ Edo láti kọ́ ẹ̀kọ́ fún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa "Sociology" àti "Anthropology". Ó ṣe àwárí ọgbọ́n rẹ̀ ní ìlù lílù ní ọdún 1991 pẹ̀lú atẹ̀le nípa gbígbé "rapping" ní ọdún 1994. Lẹ́hìn náà ó dá ẹgbẹ́ kan tí a pè ní “Da Psychophats” tí ó ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méje àti pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ fún eré àti "rapping" ní ọdún 1995, síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n yapa ṣáájú ìdásílẹ̀ èyíkéyìí ohun èlò k'ọkan. Ó tẹ̀síwájú láti dá ẹgbẹ́ "rap" mìíràn tí a mọ̀ sí "Da Oddz" pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ Godwin àti Muyiwa Ola-Phillips: wọ́n ṣe eré bíi mélòó kan ṣùgbọ́n wọn kò kógojá nítorí àmì ìyasọ́tọ̀ ti "rap" wọn kò ṣéé gbà ní Nàìjíríà.[3]
Ẹ̀kọ́ Rẹ̀
àtúnṣeBright parí ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀ ní Apapa (Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà) lẹ́yìn náà ó lọ gbóyè ní Yunifásítì ti Benin níbi tí ó ti ka ẹ̀kọ́ sociology ati anthropology pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ Godwin.[4]
Àwọn Ìfarahàn
àtúnṣeIn 2000, Basketmouth appeared in Lagbaja music video titled Gra Gra.
Ní ọdún 2005 àti 2006, Basketmouth gba Ààmì Ẹ̀yẹ Àpanilẹ́rìín ti Orílẹ̀-èdè àti àwọn ẹ̀bùn fún Àpanilẹ́rìín Ìdúró tí ó dára jùlọ ti ọdún náà.
[5] Ó jẹ́ yíyan ní ẹ̀dá ọdún 2021 "maiden edition of The Humour Awards Academy" lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpanilẹ́rìín ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ Mr Funny. [6]
Basketmouth farahàn nínú iṣàfihàn Africa Magic "My Flatmates" ní ọdún (2016).
Láìpẹ́ yìí Basketmouth ti gbàlejò olówó àti ọlọlà Nàìjíríà Femi Otedola ní ilé rẹ̀. [7]
Ní Oṣù Kejìlá ọdún 2020, ó bẹ̀rẹ̀ jara eré àwàdà rẹ̀ ti àkọ́lé “Papa Benji”[8]
Ayé Tirẹ̀
àtúnṣeNí Oṣù kọkànlá ọdún 2010, Basketmouth fẹ́ ọ̀rẹ́-bìnrin rẹ̀ tipẹ́ Elsie ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà. Wọ́n ní ọmọ mẹ́ta papọ̀. Ní Oṣù Kejìlá ọdún 2022, Basketmouth kéde nípasẹ̀ àkọọlẹ Instagram iṣẹ́ rẹ̀ pé òun àti ìyàwó rẹ̀ ń kọ́ ara wọn sílẹ̀ lẹ́hìn ọdún méjìlá ti ìgbéyàwó. [9] [10]
Àwọn Ààmì Ẹ̀yẹ Àti Yíyan
àtúnṣeYear | Award | Category | Work | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2022 | Africa Magic Viewers' Choice Awards | Best Africa Magic Original Comedy Series | My Flatmates | Wọ́n pèé | [11] |
Àwọn Ìtọ́ka Sí
àtúnṣe- ↑ MTVBase (2013-11-22). "Basketmouth arrested in the UK". MTVBase. Retrieved 2013-11-22.
- ↑ BellaNaija.com (2021-07-16). "Superstar Comedian Basketmouth serves "Ghana Jollof" – Here's How You can Audition for the Showmax Original". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-08-11.
- ↑ "Comedian BASKETMOUTH Full Biography,Life And News". T.I.N. Magazine. 19 July 2015. Retrieved 10 August 2016.
- ↑ Informationng (2014-08-02). "Basketmouth's Book: Before I Write A Book Part 2". Informationng. Retrieved 2014-08-02.
- ↑ Abisola Alawode & Jumoke Rufus (2014-01-10). "What Did Basketmouth Do Wrong?". Leadership. Archived from the original on 2014-02-23. Retrieved 2014-01-10. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ vanguardngr.com (2021-10-06). "The Humour Awards Academy releases nomination list-Vanguard". Vanguard (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-09.
- ↑ "Basketmouth Hosts Billionaire, Femi Otedola in His Home – Premium Times International". Archived from the original on 2018-07-31. Retrieved 2018-07-31. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "It's Finally Here! Watch the First Episode of Basketmouth's Comedy Series "Papa Benji"". BellaNaija. BNTV. 2020-12-14. Retrieved 2021-02-18.
- ↑ "Comedian Basketmouth Missing in the Cut As Wife Elsie Releases Family Christmas Photo With Their Children". Legit.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-12-25. Retrieved 2022-12-27.
- ↑ "Comedian, Basketmouth, announces marriage crash". Vanguard NGR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-12-23. Retrieved 2022-12-27.
- ↑ "Queen Osas, best actress, AMVCA 2022". The Cable NG. https://www.thecable.ng/queen-osas-best-actress-amvca-2022.