Àwọn èdè Bẹ́núé-Kóngò

(Àtúnjúwe láti Benue-Congo languages)

Ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èdè yìí ni: Ìwọ̀-oòrùn àti Ìlà oòrùn Benue-Congo. Àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀ ni ó ní àwọn èèyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí, ó sì sodo sí apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìlú bíi Cameroon, Congo, CAR, DRC, Tonzania, Uganda, Kenya, Mozambique, Angola, Rwanda, Burundi, Namibia, Zambia, Malawi, Zimbabwe, Gabon, Lesotho, Samalia àti àwọn èdè yìí kalẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe wádìí rẹ̀, èdè Yorùbá àti Igbo ni ó tóbi jùlọ nínú ẹ̀ka èdè tí a pè ní Benue-Congo, ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Benue-Congo ni ó sì pín àwọn èdè wọ̀nyí sí. Àtẹ náà nìyí. Fig 2.11. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Benue-Congo’ ti o pín sí ìsọ̀rí meji pàtàkì.

Benue-Congo
Ìpínká
ìyaoríilẹ̀:
Subsaharan Africa, from Nigeria east and south
Ìyàsọ́tọ̀:Niger-Kóngò
Àwọn ìpín-abẹ́:
[[File:Some important branches of the Volta-Niger and Benue-Congo families are concentrated in Nigeria, Cameroon, and Benin.|350px]]

(a) Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo

(b) Ìlà oòrùn Benue Congo

Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo:- Ó pín sí YEAI (Yoruboid, Edoid, Akokoid, Igboid); Akpes; Ayere-Ahan; NOI (Nupoid, Ọkọ, Idomoid). Ìlà oòrùn Benue Congo :- Ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta pàtó.

(a) Àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíráà:- Ó pín sí: Kainji, Àríwá-Ìwọ̀ Plateane, Beromic, Àárín gbùngbùn Plateane, Ìlà-oòrùn Gúúsù Plateane, Tarok, Jukunoid.

(b) Ukaan

(d) Bantoid-Cross:- Lábẹ́ èyí ni Bantoid ti yapa. Nígbà tí a sì rí Cross River ní abẹ́ Bantoid-Cross. Láti ara Cross River ni Bandi ti wá yapa. Nígbà tí a wá rí Delta-Cross lábẹ́ Cross River. Ní ìparí, ó fihàn gbangba wí pé èdè Niger-Congo tóbi tààrà àti wí pé orílẹ̀ èdè Áfíríkà ni ó pẹ̀ka sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó gbalẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n a rí lára wọn tí ìgbà ti fẹ́rẹ̀ tan lórí wọn. Àwọn wọ̀nyí ni èdè mìíràn ti fẹ́ máa gba saa mọ lọwọ Àwọn ìdí bíi, òṣèlú, ogun, òlàjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sì ṣe okùnfà èyí. Ní pàtàkì jùlọ, gbogbo èdè yìí náà kọ́ ni àwọn Lámèyítọ́ èdè fi ohùn ṣe ọ̀kan lé lórí lábẹ́ ìsòrí tí wọ́n wa ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ‘ẹbí’ rẹ fi ojú hàn gbangba. Ní ìparí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí rẹ̀ ṣùgbọ́n ààyè sì tún sí sílẹ̀ fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ túlẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí àti lámèyítọ́ lórí ẹ̀kà èdè Niger-Congo.