Bettinah Tiana (bíi ni ọjọ́ kẹwàá oṣù kọkànlá ọdún 1993) jẹ́ òṣèré, mọ́dẹ́lì àti agbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórílẹ̀ èdè Uganda. Ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí atọ́kun fún ètò Youth Voice, Be My Date[1] àti The Style Project. Ó kọ ipa Rhona nínú eré The Hostel.

Bettinah Tianah
Ọjọ́ìbíBetty Nassali
10 Oṣù Kọkànlá 1993 (1993-11-10) (ọmọ ọdún 31)
Uganda
Orílẹ̀-èdèUgandan
Ẹ̀kọ́St. Mary’s College Kitende; Makerere University Business School; Cavendish University Uganda
Iṣẹ́TV Presenter; actress; fashion model

Iṣẹ́

àtúnṣe

Tianah bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe atọ́kun fún ètò Youth Voice láti ìgbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún. Lẹ́hìn náà, ó ṣe atọ́kun fún ètò Be My Date[2][3]. Tianah bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí Rhona ní eré The Hostel. Òun ní ó ṣe atọ́kun fún ayẹyẹ UNAA Convention ní ìlú Washington D.C.[4] Ó darapọ̀ mọ́ Creative Industries Group ní ọdún 2017, gẹ́gẹ́ bí mọ́dẹ́lì fún wọn.[5]

Ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Tianah gboyè nínú ìmò ìròyìn láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Cavendish University.[6]

Àwọn Ìtọ́kàsi

àtúnṣe