Bezunesh Bekele Sertsu ni a bini ọjọ kọkan dinlọgbọn, óṣu January, ọdun 1983 jẹ elere sisa lóbinrin órilẹ Ede Ethiopia to da lori marathon[1].

Bezunesh Bekele
Bezunesh Bekele at the 2009 Boston Marathon
Òrọ̀ ẹni
Orúkọ kíkúnrẹ́rẹ́Bezunesh Bekele Sertsu
Ọmọorílẹ̀-èdèEthiopian
Ọjọ́ìbí29 Oṣù Kínní 1983 (1983-01-29) (ọmọ ọdún 41)
Addis Ababa
Height1.45 metres (4 ft 9 in)
Sport
Erẹ́ìdárayáRunning
Event(s)cross-country running

Àṣèyọri

àtúnṣe

Bekele kopa ninu ere ti Montferland ni ọdun 2004 ati 2005. Ni ọdun 2006, Arabinrin naa kopa ninu idije agbaye ti IAAF cross country pẹlj ipo kẹfa. Ni ọdun 2007, Bekele yege ninu Zevenheuvelenloop ati Idaji Marathon ti Portugal. Ni ọdun 2007, Bekele kopa ninu idije Agbaye ti oju ọna ti IAAF pẹlu wakati 1:08:07[2]. Ni ọdun 2008, Arabinrin naa gbe ipo kẹta ninu ere ti Manchester[3]. Ni ọdun 2008, Bekele kopa ninu Marathon ti Dubai to si gbe ipo keji pẹlu wakati 2:23:09. Ni ọdun 2009, Bekele kopa ninu idije agbaye lori ere sisa nibi to ti pari pẹlu ipo kẹrin dinlogun. Ni óṣu April, ọdun 2010, Bekele kopa ninu Marathon ti London to si pari pẹlu ipo kẹrin pẹly wakati 2:23:17[4]. Ni óṣu September, ọdun 2010, Bekele kopa ninu Marathon ti Berlin pẹlu wakati 2:24:58 to si pari pẹlu ipo keji[5]. Ni ọdun 2011, Arabinrin naa kopa ninu idije agbaye to si pari pẹlu ipo kẹrin. Ni ọdun 2012, Bekele kopa ninu Marathon ti Dubai pẹlu wakati 2:20:30 to si pari pẹlu ipo kẹrin[6]. Ni óṣu April, ọdun 2012, Bekele kopa ninu Idaji Marathon ti Yangzhou to si pari pẹlu ipo kẹrin. Arabinrin naa gbe ipo kẹrin ninu Marathon ti Frankfurt.

Itọkasi

àtúnṣe
  1. Bekele Profile
  2. 2007 IAAF
  3. The Great Manchester Run
  4. London Marathon
  5. Berlin Marathon
  6. Dubai Marathon