Bím̀bọ́ Ọ̀ṣìn (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje ọdún 1971) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Oǹdó lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Bím̀bọ́ Ọ̀ṣìn
Ọjọ́ìbíAbimbola Oshin
24 Oṣù Keje 1971 (1971-07-24) (ọmọ ọdún 52)
Ondo State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1996-present

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú pé wọ́n bí Bím̀bọ́ Ọ̀ṣìn lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje ọdún 1971 ni ìpínlẹ̀ Oǹdó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà , ó kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ Philosophy.[1] Bím̀bọ́ Ọ̀ṣìn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 1996[2] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni eré sinimá àgbéléwò tí ó ti kópa ṣùgbọ́n ìràwọ̀ rẹ̀ tán síta lẹ́yìn tí ó kópa pàtàkì nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Ọmọ Ẹlẹ́mọ̀ṣọ́" lọ́dún 2012. [3]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Why I sometimes throw caution to the winds-Bimbo Oshin". Nigerian Tribune. Archived from the original on 19 February 2015. Retrieved 20 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Bimbo Oshin!". Ibaka tv. Archived from the original on 2015-02-24.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "10 celebrities we can’t get enough of….". Vanguard News. Retrieved 20 February 2015.