Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù karùn-ún ọdún 1959, ni wọ́n bí Binta Nyako ní ìjọba ìbílẹ̀ Remawa, ní ìpínlẹ̀ Katsina.

Wọ́n bí i sí ilé ẹbí tí wọ́n gbìyànjú láti ṣètò ayé wọn. Ó dàgbà, ó sì lọ sí ilé-ìwé ní Bauchi nígbà náà. Ó gbìyànjú láti gba ẹ̀kọ́ tó yẹ yálà àwọn ìṣòro tó dojú kọ. Èyí ló sì mú kí iṣẹ́ rẹ̀ gboyè nísìínìn. [1]

Ẹ̀kọ́ Rẹ̀

àtúnṣe

Ní ìtẹ̀lé ìwọlé rẹ̀ sí Queens College ní Yaba, ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà. Ó gba satífíkéètì àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1976. Ó lọ sí Fásítì Ahmadu Bello ní Zaria , níbi tó ti gba LLB dìgírì nígbà tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin. [1]

Ayé Binta Nyako, Ọkọ Rẹ̀ Àti Ẹbí Rẹ̀

àtúnṣe

Ó jẹ́ ìyàwó ìkẹrin ti Vice Admiral - Murtala Nyako, gómìnà ológun ti tẹ́lẹ̀ ti Ìpínlẹ̀ Niger láti oṣù kejì ọdún 1976 sí oṣù kejìlá ọdún 1977. Ó tún jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Adamawa ti tẹ́lẹ̀ láti ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2008 sí ọjọ́ karùn-ún dín lógún oṣù keje ọdún 2014 wọ́n sì mú u kúrò nípò lẹ́hìn náà.

Ó bímọ méjì pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní Bauchi ṣáájú kí ó tó pàdé Murtala, tí wọ́n sì wà pẹ̀lú bàbá wọn. Ó tún ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìyá ìyá ti ọmọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ síi, ṣùgbọ́n kò tí ì mẹ́nuba rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀ nítorí ó n'ífẹ lati tọjú ìgbésí ayé ara rẹ̀ ní ìkọkọ. [1]

Àwọn Ìtọ́ka Sí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 Ndagi, Aliyu (2023-03-07). "Justice Binta Nyako Net Worth, Biography, Age & Husband". NupeBaze. Archived from the original on 2023-03-10. Retrieved 2023-03-10.