Biochemistry
Biochemistry, nígbàmíràn wọ́n máa ń pèé ní biological chemistry, jẹ́ ìmọ̀ ìlànà kẹ́míkà àgọ́ ara àtí ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú ohun ẹlẹmí.[1] Nípa ṣíṣe àkóso lílọ-bíbọ̀ iṣẹ́ lágọ́ ara nípasẹ̀ ìtalólobo ìbáṣepọ̀ kẹ́míkà àti lílọ-bíbọ̀ agbára kẹ́míkà làtàrí gbogbo ìbáṣepọ̀ kẹ́míka nínú ara, ìlànà kẹ́míkà nínú ara yìí ní ó máa ń ṣe ìmúgbòòrò bí ara ṣe ń ṣiṣẹ́. Ní bíi ogún ọrundún sẹ́yìn, biochemistry ti ṣe àṣeyọrí lórí bí a ṣe lè ṣàlàyé lórí ìlànà ìgbéayé tí ó ni ṣe pẹ̀lú ìmọ ohun ẹlẹ́mí làti ìmọ̀ ewéko sí ìmọ̀ ìlera, sí ìmọ̀ ìṣiṣẹ́àbínimọ́ ní wọ́n ní ṣe pẹ̀lú ìwádí ìbáṣepọ̀ kẹ́míkà lágọ́ ara.[2] Loní, ìdojúkọ ìwádí ní biochemistry dá lórí òye bí biological molecules ṣe ń f ìlànà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ètò ẹ̀yà ara.[3]