Blanche Bilongo

Blanche Bilongo (tí a bí ní 26 Oṣù Kínní, Ọdún 1974) jẹ́ òṣèrébìnrin, ònkọ̀tàn, àti olóòtú ọmọ orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.

Blanche Bilongo
Ọjọ́ìbíOṣù Kínní 26, 1974 (1974-01-26) (ọmọ ọdún 48)
Monatélé
Orílẹ̀-èdèCameroonian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Yaoundé II
Iṣẹ́Actress, screenwriter, presenter, film editor
Ìgbà iṣẹ́2000-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀Àtúnṣe

Bilongo wá láti agbègbè-ààrin ti orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.[1] Ó lọ sí ilé-ìwé Johnson College ní ìlú Yaoundé níbi tí ó ti ṣe àwọn eré ijó. Ní ọdún 1987, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ sí àwọn àtúnyẹ̀wò ẹgbẹ́ ìṣeré orí ìtàgé ti André Bang tí wọ́n pe orúkọ wọn ní Les Pagayeurs. Níbè ló ti há àwọn ọ̀rọ̀ tó wà fún akópa olú-ẹ̀dá-ìtàn sórí. Ní ọjọ́ kan tí wọ́n ṣàfẹ́rí akópa olú-ẹ̀dá-ìtàn náà, Bilongo rọ́pò rẹ̀ láti kó ipa náà, èyí tí ó fun ní ànfàní láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà.[2]

Bilongo kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu fíìmù Tiga, L'Héritage ní ọdún 2000.[3] Ní ọdún 2005, Bilongo kópa gẹ́gẹ́ bi Sabine nínu eré tẹlifíṣònù N'taphil.[2] Bákan náà ní ọdún 2007, ó kópa gẹ́gẹ́ bi Pam nínu eré Hélène Patricia Ebah kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les Blessures Inguérissables. [4] Ó di olóòtú fún ìkànnì tẹlifíṣọ̀nù CRTV ní ọdún 2009.[5]

Ní ọdún 2019, Bilongo ṣe àgbéjáde àkọ́kọ́ orin àdákọ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ n jẹ́ "Le temps de Dieu". Ó kọ orin náà ní èdè Beti fún ìyá rẹ̀ tí ó ti di olóògbé.[6] Ní ọdún 2020, ó kópa gẹ́gẹ́ bi Marie Young nínu eré aláwàdà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Coup de Foudre à Yaoundé.[7]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀Àtúnṣe

 • 2000 : Tiga, L'Ipejuwe
 • Ọdun 2006 : Mon Ayon : Eda
 • Ọdun 2006 : Enfant Peau Rouge : ayaba
 • 2007 : Les Blessures Inguérissables : Pam
 • Ọdun 2010 : Les Bantous vont au Cinéma
 • 2011 : Deuxième Bureau
 • 2020 : Coup de Foudre à Yaoundé : Marie Young

Àwọn ìtọ́kasíÀtúnṣe

 1. "Cameroon: Final Touches For Reunification Cultural Activities :: Cameroun". 237online. 17 December 2013. Retrieved 11 October 2020. 
 2. 2.0 2.1 "Cameroun: Blanche Bilongo : le beau rôle". 15 April 2005. https://fr.allafrica.com/stories/200504150745.html. Retrieved 11 October 2020.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "atanga" defined multiple times with different content
 3. "Cameroun: Fiction - Les Bantous vont au cinéma" (in French). 1 June 2010. https://fr.allafrica.com/stories/201006011218.html. Retrieved 11 October 2020. 
 4. "Yaoundé : Un week-end de danse et de comédie" (in French). 10 November 2007. http://www.cameroon-info.net/article/yaounde-un-week-end-de-danse-et-de-comedie-106911.html. Retrieved 11 October 2020. 
 5. "Musique: Blanche Bilongo rend hommage à sa mère". Crtv.cm (in French). 14 February 2019. Retrieved 11 October 2020. 
 6. "Musique: Blanche Bilongo rend hommage à sa mère". Crtv.cm (in French). 14 February 2019. Retrieved 11 October 2020. 
 7. "Coup de Foudre à Yaoundé". Orange.fr (in French). Retrieved 11 October 2020. 

Àwọn ìtakùn ÌjásódeÀtúnṣe