Bokku!
Bokku! Mart, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Bokku! èyí tí ó túmọ̀ sí ọ̀pọ̀ jẹ́ ẹ̀ka ilé ìtajà ìnáwó alágbára tí a ṣe nípasẹ̀ àwòkọ́ṣe kan tí ó jọra ní Germany, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹsàn án , ọdún 2022. [1]
Ohun tí wọ́n ń ṣe
àtúnṣeÓ jẹ́ ohun ìní nípasẹ̀ Atreos Limited, pẹpẹ ìdókòowò àwọn ilé ìtajà Bokku! ó ń ta ìwọ̀nba àwọn ọjà ìjẹun tí wọ́n ti fara balẹ̀ yan. Àwọn ọjà wọ̀nyí jẹ́ èyí tó dára jùlọ àti pé ó bá àwọn àìní òjoojúmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní Nàìjíríà. Lára wọn ni àwọn ohun mímu, ìtọ́jú ara àti àwọn ohun èlò ìtọ́jú ilé bíi ọṣẹ, àwọn ohun èlò ìfọṣọ, ìtọ́jú eyín pẹ̀lú ìrẹsì àti òróró tí ó wà lára àwọn ohun tí gbogbo ọmọ Nàìjíríà nílò. [2]
Oríṣìíríṣìí Ọgbà ìtajà náà
àtúnṣeÀwọn ilé ìtajà àjọ yìí tàn káàkiri ìlú Èkó, àwọn oníbàárà tí ó nílò àwọn nǹkan tí wọ́n ń rà lójoojúmọ́ sì ń wá wọn kiri báyìí. Lára ibi tí ilé ìtajà yìí wà ni wọ̀nyí: Jonathan Coker, Fagba; Ọ̀nà College, Ogba; Ọ̀nà Iju, Ishaga; Ọ̀nà Agbado, Jankara; Santos Avenue, Oko-Oba àti Òpópónà Aina, Ojodu Berger, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [2]
Ohun tí wọ́n gbajúmò fún
àtúnṣeYàtọ̀ sí èyí, ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ilé ìtajà náà ti lè ṣe àbájáde rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ búrẹ́dì àkànṣe rẹ̀, èyí tí àwọn oníbàárà rí pé kò níye tó pọ̀jù lórí ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ọjà mìíràn àti bó ṣe dùn tó àti bó ṣe jẹ́ ọlọ́wọ̀n tó. Wọ́n ti ṣàkíyèsí pé ibi tí àwọn ènìyàn máa ń lọ jùlọ ní Bokku Mart ni ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe búrẹ́dì, níbi táwọn oníbàárà ti máa ń tò sórí ìlà fún ọ̀pọ̀ wákàtí nígbà míì kí wọ́n lè ra búrẹ́dì kan ṣoṣo.[2]
Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Best Discount Grocery Store in Nigeria". bokku!. 2024-06-25. Retrieved 2024-09-17.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 "Bokku challenges Shoprite, Spar, other super malls’ dominance". Business Hallmark - Business Hallmark - breaking business, politics and finance news. 2024-03-04. Retrieved 2024-09-17.