Bola Akindele
Adebola Ismail Akindele (tí a bí ní oṣù kọkànlá ọjọ́ karùn-dín-lọ́gbọ̀n, ọdún 1963) ní Ibadan, Ìlú Ọ̀yọ́ jẹ́ òǹtajà, onímọ̀ràn ìṣòwò àti onínúure. Ó jẹ́ Olùdárí Alákoso Ẹgbẹ́ ti Courteville Business Solutions, olùpèsè ti ìmọ̀-ẹ̀rọ àlàyé àti àwọn iṣẹ́ ìjáde ìlànà ìṣòwò.[1] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti ìgbìmọ̀ àwọn alámọ̀ràn ti East Africa Business Network (EABN).[2][3] Ó wà ní ìdánimọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn "ọ̀kàn-lé-lógún tó wà ní òkè eré wọn", nípasẹ̀ ìwé ìròyìn African Business Central magazine.[4]
Bola Akindele | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Adebola Ismail Akindele. November 25, 1963. Ibadan, Oyo State, Nigeria. |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Obafemi Awolowo University University of Lagos International School of Management (ISM) London Business School Lagos Business School |
Iṣẹ́ | Businessman, Strategist, Philanthropist. |
Olólùfẹ́ | Olabisi Sidiquat Akindele |
Àwọn ọmọ | 4 Children |
Website | http://bolaakindele.com |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀ Àti Ẹ̀kọ́
àtúnṣeỌjọ́ karùn-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá, ọdún 1963 ni wọ́n bí Bola Akindele ní ìlú Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ó dàgbà ní Èkó, ní Ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó sì lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Ansar-Ud-deen, ní Ìsọlọ̀, ní Èkó láti ọdún 1974 sí ọdún 1979. Ó jẹ́ ọmọ ilé ìwé gíga Fásìtì Obafemi Awolowo, Ilé-ifẹ̀ níbi tí ó ti gbóyè pẹ̀lú Bachelor of Arts ní iṣẹ́ àgbẹ̀. Ó gba oyè "masters" ní Banking & Finance láti Fásìtì ìlú Èkó tí à ń pè ní "University of Lagos" ní ọdún 1993 àti pé ó tún gba oyè Doctorate of Business Administration (DBA) láti International School of Management, Paris. Ó tún jẹ́ ọmọ tó jáde láti Ilé-ìwé Ìṣòwò Ìlú London (London Business School) àti Ilé-ìwé Ìṣòwò Ìlú Èkó (Lagos Business School.)[5][6]
Ayé Rẹ̀ Gangan
àtúnṣeBola Akindele ní àwọn oyè ìbílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóyè Otúnba Tayese ti Ilẹ̀ Ogijo ní ìpínlẹ̀ Èkó, àti ti Otúnba Bobaselu ti Ilẹ̀ Ejirin ní Epe, ní Èkó. Wọn fún un ní oyè Islam ti Balógun Adinni ti Ọlọ́run Gbẹ̀bẹ̀ Central Mosque ní Muṣin ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Ó ṣe ìgbéyàwó sí Olabisi Sidiquat Akindele. Wọ́n ní ọmọ mẹ́rin, wọn sì jẹ́ ara ẹgbẹ́ Ìkòyí Club ní Èkó.
Àwọn Ìtọ́ka Sí
àtúnṣe- ↑ Insight, Asoko. "Courteville Business Solutions Posts $1 Million Profit (Nigeria)". www.asokoinsight.com. Retrieved 3 August 2015.
- ↑ News, Sun. "EABN appoints Courteville's Akindele to its board". Sun News. http://sunnewsonline.com/new/eabn-appoints-courtevilles-akindele-to-its-board/. Retrieved 3 August 2015.
- ↑ Ojo, Olawunmi (January 14, 2015). "East Africa Business Network appoints Akindele to board". The Guardian Newspapers. http://www.ngrguardiannews.com/2015/01/east-africa-business-network-appoints-akindele-to-board/. Retrieved 3 August 2015.
- ↑ African Business Central. "21 Nigerian tech CEOs at the top of their game". www.africanbusinesscentral.com/. Archived from the original on 30 July 2015. Retrieved 3 August 2015.
- ↑ Akindele, Bola. "Bola Akindele". bolaakindele.com. Retrieved 3 August 2015.
- ↑ Foundation, PE Brahim. "Trustees & Executive Committee". Archived from the original on 24 September 2015. Retrieved 3 August 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)