Bọ́lájí Amúṣàn-án tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Mr. Látìn tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹwàá ọdún 1966 (October 15th, 1966) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré aláwàdà àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí Yorùbá ti ìlú Gbọ̀ngán ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà .[1][2]

Bọ́lájí Amúṣàn-án
Ọjọ́ìbíBọ́lájí Amúṣàn-án
(1966-10-15)15 Oṣù Kẹ̀wá 1966
Gbongan, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun , Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Orúkọ mírànMr Latin
Ọmọ orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Iṣẹ́
  • òṣèré aláwàdà sinimá àgbéléwò
  • comedian
Ìgbà iṣẹ́1988–present
Olólùfẹ́Rónkẹ́ Amúṣàn-án
Àwọn ọmọ2


Ìgbà èwe àti aáyan ìṣe tíátà rẹ̀

àtúnṣe

Ìlú kan tí ó ń jẹ́ Gbọ̀ngán ni wọ́n bí ní Bọ́lájí Amúṣàn-án sí ní Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹwàá ọdún 1966. Gbọ̀ngán jẹ́ olú-ìlú Ìjọba ìbílẹ̀ Ayédáadé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [3] Ó fẹ́ Ìyàwó rẹ̀ Rónkẹ́ Amúṣàn-án lọ́dún 1999 [4] wọ́n bímọ méjì fún ara wọn. MR. Látìn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 1988, lọ́dún 1992 ni ó kópa pàtàkì nínú eré kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "50 50". Àgbà òṣèré sinimá àgbéléwò àti Akin Ògúngbè ni ó kọ sinimá náà. Lọ́dún 1989 ló dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò tí wọ́n ń pè ní ANTP. [5][6] Láti ìgbà náà, Bọ́lájí Amúṣàn-án tí kópa nínú àìmọye sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá. Ipa aláwàdà ni ó sáàbà máa ń kó jùlọ. Òun ní Alága àti olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ Mr. Latin TV àti Mr. Latin Foundation.

Àtòjọ díẹ̀ nínú àwọn sinimá-àgbéléwò rẹ̀

àtúnṣe
  • 50-50 (1992)
  • Ebun Igbeyawo (1996)
  • Faworaja (1999)
  • Nnkan Olomoba (2000)
  • Talo n gbemu (2001)
  • Eegun Mogaji
  • Obajobalo
  • Mr President
  • Òfin mósè (2006).
  • Ile Itura (2007)[7]
  • Baba Insurance (2009),
  • Ise onise (2009)
  • Baba Gomina[1]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "My dream was to become a footballer — Mr. Latin — Vanguard News". Vanguard News. Retrieved 20 February 2015. 
  2. webmaster. "Bolaji Amusan (Mr Latin): Actor, comedian loved by fans — Newswatch Times". Newswatch Times. Archived from the original on 4 March 2016. Retrieved 20 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "I’m not a comedian at home –Bolaji Amusan". The Punch — Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 22 February 2015. Retrieved 20 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "‘I Once Told My Wife To Leave Me When I Had No Money To Take Care Of Her’ -Baba Latin" (in en-US). Nigerian Celebrity News + Latest Entertainment News. 2016-11-28. https://stargist.com/entertainment/nigerian_celebrity/baba-latin-and-wifebaba-latin-marriagebaba-latin-family/. 
  5. "Archived copy". Archived from the original on 2015-02-20. Retrieved 2015-02-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "My dream was to become a footballer - Mr. Latin - Vanguard News" (in en-US). Vanguard News. 2011-05-14. https://www.vanguardngr.com/2011/05/my-dream-was-to-become-a-footballer-mr-latin/. 
  7. Ile itura, retrieved 2018-09-17