Bọ́láńlé Nínálowó tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ní ó (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún 1980) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò àti onímọ̀ Ìsirò-owó ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n tí ó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Bí ó ṣe ń ṣeré tíátà, bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ akọrin. [1][2][3]

Bolanle Ninalowo
Bolanle Ninalowo at the 2020 AMVCA
Ọjọ́ìbí7 Oṣù Kàrún 1980 (1980-05-07) (ọmọ ọdún 44)
Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànNino
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigeria
Iléẹ̀kọ́ gígaDeVry University
Iṣẹ́Actor
Ìgbà iṣẹ́2010–present

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

àtúnṣe

A bí Nínálowó sí ìlú Ìkòròdú ni ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Kí óó dèrò ìlú-ọba ó kàwé àkóbẹ̀rẹ̀ àti sẹ̀kọ̀ndìrì rẹ̀ ní ìlú Èkó.[4]

Ìgbìyànjú nídìí ìṣe sinimá àgbéléwò

àtúnṣe

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ síwájú, Nínálowó jẹ́ onímọ̀ Ìsirò-owó, nítorí ìdí èyí, ó kọ́kọ́ ṣíṣe ni ilé-ìfowópamọ́ gẹ́gẹ́ bí Aṣèṣirò-owó (Accountant) fún ìgbà díẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí ó tó dára pọ̀ mọ́ ìṣe eré sinimá àgbéléwò ṣíṣe lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bákan náà, nígbà tí ó padà sí Nàìjíríà, ó tún bá ilé-ìfowópamọ́ Guaranty Trust Bank ṣíṣe kí ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà. Nínálowó kò fi bẹ́ẹ̀ rọ́wọ́ mú nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò gẹ́gẹ́ bí olóòtú, ṣùgbọ́n lọ́dún 2014, ní ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá di gbajúmọ̀ nídìí ìṣe sinimá àgbéléwò.[5] [6]

Àwọn àmìn ẹ̀yẹ tí ó ti gbà àti àwọn tí wọ́n dárúkọ díje rẹ̀ fún

àtúnṣe
  • Revelation of the Year, Best of Nollywood Award, 2010
  • Best Supporting Actor of the Year ‘English’, City People Movie Award, 2017[7]
  • The Best Actor in a Leading Role ‘English‘ Picture Perfect’ Best of Nollywood Awards (BON), 2017
  • Best Actor of the Year ‘English’ City People Movie Award, 2018
  • Best Actor of the Year ‘English’, City People Movie Award, 2018


Àtòjọ díẹ̀ nínú àwọn sinimá-àgbéléwò tí ó ti kópa

àtúnṣe


Awon àmì ẹ̀yẹ

àtúnṣe
Year Award ceremony Prize Result Ref
2010 Best of Nollywood Awards Revelation of the Year Gbàá
2017 City People Movie Award Best Supporting Actor of the Year - English Gbàá [8]
Best of Nollywood Awards Best Actor in a Lead role - English Gbàá [9]
2018 Best of Nollywood Awards Best Actor in a Lead Role - Yoruba Wọ́n pèé
City People Movie Award Best Actor of the Year - English Gbàá

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Why my marriage failed –Bolanle Ninalowo". Newtelegraph. 2017-12-31. Archived from the original on 2019-12-21. Retrieved 2019-12-17. 
  2. Nigeria, Information (2018-03-21). "My success story in Nollywood – Bolanle Ninalowo". Information Nigeria. Retrieved 2019-12-17. 
  3. Bada, Gbenga (2015-05-13). "Rukky Sanda’s cousin becomes Nollywood’s new toast". Pulse Nigeria. Archived from the original on 2019-12-17. Retrieved 2019-12-17. 
  4. "Bolanle Ninalowo biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 1980-05-07. Retrieved 2019-12-17. 
  5. "Bolanle Ninalowo Biography & Net Worth". 360dopes. 2018-07-20. Retrieved 2019-12-17. 
  6. "BOLANLE NINALOWO: WHY I SEPARATED FROM THE MOTHER OF MY KIDS - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2017-11-03. Retrieved 2019-12-17. 
  7. Emmanuel, Daniji (2017-10-18). "Full List Of Winners At The 2017 City People Movie Awards". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-23. 
  8. Emmanuel, Daniji (18 October 2017). "Full List Of Winners At The 2017 City People Movie Awards". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 23 November 2019. 
  9. "BON Awards 2017: Kannywood’s Ali Nuhu receives Special Recognition Award". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 23 November 2017. Retrieved 7 October 2021.