Bonnie Mbuli
Bonnie Mbuli (bíi ni ọjọ́ kẹta oṣù kẹta ọdún 1979[2]) jẹ́ òṣèré, agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ati ọlọ́jà ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà. Ó ṣe atọkun fun ètò Afternoon Express. Ní ọdún 2020, ó kó ipa Jasmine Hadley nínú eré Nought and Crosses tí BBC gbé jáde.
Bonnie Mbuli | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹta 1979 Soweto, South Africa |
Orúkọ míràn | Bonnie Henna |
Ẹ̀kọ́ | Belgravia Convent[1] Greenside High School |
Iṣẹ́ | |
Olólùfẹ́ | Sisanda Henna (m. 2005; div. 2013) |
Àwọn ọmọ | 2 |
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí sì ìlú Soweto ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà ni ọdún 1979. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Dominican Convent School àti Greenside High School ni ìlú Johannesburg. Òun ni àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ mẹ́ta tí àwọn òbí rẹ bí.
Iṣẹ́
àtúnṣeÓ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe eré nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹtàlá, ó sì kópa nínú eré Viva Families ni ọdún 1992.[3]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- Invictus (2009)
- Catch A Fire (2006)[4]
- Drum (2004)
- Gaz'lam (13 episodes, 2003–2004)
- Traffic! 12 February (2014)
Igbe ayé rẹ̀
àtúnṣeMbuli fẹ́ òṣèré àti agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí orúkọ rẹ jẹ́ Sisanda Henna, wọn sì ní ọmọ méjì. Leyin ti wọn pínyà, ó kọ ìwé ìtàn nípa ayé rẹ̀.[5]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Dominican Convent School". dominican.co.za.
- ↑ Julie Kwach (16 August 2019). "Bonnie Mbuli biography:age, husband, boyfriend, book, and Instagram". briefly.co.za.
- ↑ "Bonnie Mbuli | TVSA". www.tvsa.co.za. Retrieved 23 May 2018.
- ↑ South Africa's Henna Is on 'Fire', Washington Post, accessed July 2013
- ↑ "Bonnie hangs out dirty linen". SowetanLIVE.