Brukina

Ọtí mílíìkì àti ọkà bàbà ní Ghana

Brukina tí a tún mọ̀ sí Burkina, ohun mímu ti Senegalese àti Ivorian. [1][2] ohun mímu tàbí ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí a fi ọkà bàbà ilẹ̀ ṣe àti mílíìkì. Brukina gbajúmọ̀ jù ní gbígbé jáde ní agbègbè àríwá ti Ghana. Ó tún jẹ́ mímọ̀ sí 'Deger'.

Àgbéyẹ̀wò

àtúnṣe

Brukina di gbígbà gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ pípé nítorí agbára rẹ̀ àti àkóónú asaralóooore tí ó.[3][4] Ó kún fún ọkà bàbà nìkan, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn irúgbìn àtijọ́, àti mílíìkì.[5]

Ṣíṣe

àtúnṣe

Brukina máa ń di ṣíṣe nípa lílo ọkà bàbà, mílíìkì màlúù ọ̀tun tàbí ẹbu mílíìkì, iyọ̀, omi àti súgà. Láti ṣe Brukina:

  • Fọ ọkà bàbà náà kí o sì rẹ ẹ́ sómi mọ́jú
  • Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, gbẹ omi náà kí o sì lọ ọkà bàbà náà sí ìrísí tí ó rí gbágungbàgun
  • Gbé omi kaná
  • Wa ọkà bàbà náà sínú alásẹ́ kí o sì fi ọwọ́ rẹ yí i títí o fi lè sọ ọ́ di bọ́ọ̀lù kéékèèké
  • Nígbà tí omi náà bá gbóná, da àwọn bọ́ọ̀lù kéékèèké ti ọkà bàbà náà sínú abọ́ kí o sì dé e pẹ̀lú ìdérí
  • De abọ́ náà dáadáa kí o sì jẹ́ kí ooru láti inú omi gbígbóná náà sè é rọ̀
  • Nígbà tí àwọn bọ́ọ̀lù kéékèèké náà bá ti rọ̀ tí wọ́n bá sì ti sè, dà á sínú abọ́ kí o sì jẹ́ kí ó tutù
  • Pò ó pẹ̀lú mílíìkì màlúù ọ̀tun tàbí ẹbu mílíìkì àti omi kí o sì pò ó papọ̀
  • Fi súgà díẹ̀ si láti lè ní adùn
  • Gbé e sínú ẹ̀rọ a-mú-nǹkan-tútù kí o sì bù ú. [1][6]

Àǹfààní ìlera

àtúnṣe

Ọkà bàbà ní in Brukina kún fún magnesium, manganese, calcium, phosphorus, Vitamin B etc.

Mílíìkì náà kún fún Vitamin D àti Calcium.[7]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "Burkina: Latest millet smoothie in town". www.ghanaweb.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-06-22. Retrieved 2019-06-22.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Recipe: Easy Steps To Prepare Burkina Drink". Modern Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-06-22. Retrieved 2019-06-22.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Burkina the Ghanaian drink you must try". Muse Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-01-26. Archived from the original on 2019-06-22. Retrieved 2019-06-22.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Dogbevi, Emmanuel (2013-09-05). "FDA trains 'Burkina' drink producers in Accra". Ghana Business News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-06-22. Retrieved 2019-06-22.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "Brukina: A nutritious food contaminated with E. coli - MyJoyOnline.com". www.myjoyonline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-16. Retrieved 2022-01-22. 
  6. "NEWS". miczd.gov.gh. Archived from the original on 2020-06-06. Retrieved 2020-06-18.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :02