Carole Karemera
Carole Umulinga Karemera (tí a bí ní ọdún 1975) jẹ́ òṣèré, oníjó, àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Rwanda.
Carole Karemera | |
---|---|
Karemera in 2015 | |
Ọjọ́ìbí | 1975 (ọmọ ọdún 48–49) Brussels |
Orílẹ̀-èdè | Rwandan |
Iṣẹ́ | Actress, dancer, saxophone player, playwright |
Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Karemera ní ọdún 1975 ní ìlú Brussels.[1] Nígbà èwe rẹ̀, Karemara jáfáfá nínu ìmọ̀ ìṣirò, ó sì maá n gbàá lérò láti ṣí ilé-iṣẹ́ búrẹ́dì.[2] Karemera kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ National Conservatory of Theatre and Dance ní ìlú Brussels. Ní ọdún 1994, bàbá rẹ̀ padà sí orílẹ̀-èdè Bẹ́ljíọ̀m nítorí ṣíṣẹ̀mílófò tí ó n ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Rwanda nígbà náà.[3] Karemera kó àkọ́kọ́ ipa nínu eré lóri ìpele ní ọdún 1996.[4] Ó sì ti wá ṣe bẹ́ẹ̀ kópa nínu àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré ìpele míràn bíi The Trojan Women látọwọ́ Euripides, The Ghost Woman látọwọ́ Kay Adshead, àti Anathema ṣááju kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe sinimá àgbéléwò. Láàrin ọdún 2000 sí 2004, ó kó ipa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Rwanda 94.[5]
Ní ọdún 2005, Karemara kópa gẹ́gẹ́ bi Jeanne nínu fíìmù Raoul Peck kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Sometimes in April.[6] Ọdún kan yìí náà ló pinnu láti máa gbé ní ìlú Kìgálì , orílẹ̀-èdè Rwanda.[1] Lẹ́hìn tí ó padà sí orílẹ̀-èdè náà, Karemara kópa nínu àwọn iṣẹ́ àkànṣe tó níṣe pẹ̀lú àṣà orílè-èdè náà. Pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Cécilia Kankonda, ó dá "sound cathedral" sílẹ̀ láti máa gba ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ ayé àwọn ènìyàn sílẹ̀ ṣáájú ọdún 1994 ní Rwanda.[7] Ní ọdún 2006, Karemara àti àwọn obìnrin méje míràn ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Ishyo Arts ní ìlú Kìgálì léte láti gbé àṣà ìlú náà larugẹ.
Karemara ti kópa gẹ́gẹ́ bi Beatrice nínu fíìmù Juju Factory ti ọdún 2007. Ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ ti òṣèré tí ó dára jùlọ níbii ayẹyẹ Festival Cinema Africano, èyí tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Itálíà.[8] Ó tún ti kọ ìwé eré táa pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Chez l'habitant", èyí tó dá lóri ìrírí àwọn obìnrin ní Ìlú Brussels, Kigali àti Sevran.[1]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- 2005: Sometimes in April gẹ́gẹ́ bi Jeanne
- 2006: Sounds of Sand gẹ́gẹ́ bi Mouna
- 2007: Juju Factory gẹ́gẹ́ bi Béatrice
- 2008: Black gẹ́gẹ́ bi Pamela
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Charon, Aurélie (12 October 2018). "Carole Karemera, j'irai le dire chez vous" (in French). Libération. https://next.liberation.fr/theatre/2018/10/11/carole-karemera-j-irai-le-dire-chez-vous_1684691. Retrieved 2 October 2020.
- ↑ "Who are the stars of Rwanda’s Hillywood?". The New Times. 11 July 2014. https://www.newtimes.co.rw/section/read/76791. Retrieved 2 October 2020.
- ↑ Bédarida, Catherine (21 April 2004). "Carole Karemera incarne la douleur des résistants tutsis" (in French). Le Monde. https://www.lemonde.fr/archives/article/2004/04/21/carole-karemera-incarne-la-douleur-des-resistants-tutsis_361953_1819218.html. Retrieved 2 October 2020.
- ↑ Charon, Aurélie (12 October 2018). "Carole Karemera, j'irai le dire chez vous" (in French). Libération. https://next.liberation.fr/theatre/2018/10/11/carole-karemera-j-irai-le-dire-chez-vous_1684691. Retrieved 2 October 2020.
- ↑ Bédarida, Catherine (21 April 2004). "Carole Karemera incarne la douleur des résistants tutsis" (in French). Le Monde. https://www.lemonde.fr/archives/article/2004/04/21/carole-karemera-incarne-la-douleur-des-resistants-tutsis_361953_1819218.html. Retrieved 2 October 2020.
- ↑ Lacey, Marc (17 February 2004). "Rwanda Revisits Its Nightmare; Filmmaker, in HBO Project, Uses Survivors and Actual Sites to Recount 1994 War". New York Times. https://www.nytimes.com/2004/02/17/arts/rwanda-revisits-its-nightmare-filmmaker-hbo-project-uses-survivors-actual-sites.html. Retrieved 2 October 2020.
- ↑ Kodjo-Grandvaux, Séverine (15 December 2016). "Carole Karemera veut reconstruire le Rwanda grâce au théâtre de rue" (in fr). Le Monde. https://www.lemonde.fr/afrique/article/2016/12/15/carole-karemera-veut-reconstruire-le-rwanda-grace-au-theatre-de-rue_5049613_3212.html. Retrieved 2 October 2020.
- ↑ Mahnke, Hans-Christian. "Review of "Juju Factory"". Africavenir. Archived from the original on 14 October 2020. Retrieved 2 October 2020.