Caroline Chikezie
Caroline Chikezie jẹ́ òṣèré ará orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti bírítìṣì, tó gbajúmọ̀ fún kíkó àwọn ipa bíi Sasha Williams nínu eré As if, Elaine Hardy nínu eré Footballers' Wives[1] àti ipa Cyberwoman nínu Torchwood
Caroline Chikezie | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 19 Oṣù Kejì 1974 London, England, UK |
Orílẹ̀-èdè | British, Nigerian |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 1998 – present |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Chikezie ní England sí àwọn òbí ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n jẹ́ elédè Igbo.[2] Ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, wọ́n rán Chikezie lọ sí ilé-ìwé bọ́dìnì ní Nàìjíríà ní ìgbìyànjú láti jẹ́ kí ó kọ àwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti di òṣèré sílẹ̀. Ṣáájú èyí, ó ti maá n lọ sí àwọn ìdánilẹ̀kọ́ ní ìparí gbogbo ọ̀sẹ̀ ní ìlu Italia Conti. Lákokò tí ó padà sí United Kingdom, ó forúkọsílẹ̀ ní Brunel University níbi tí ó ti kẹ́ẹ̀kọ́ ìṣògùn ìwòsàn ṣùgbọ́n ó fi ilé-ìwé sílẹ̀ láì gboyè. Lẹ́hìn náà ó rí ànfàní síkọ́láṣìpù si Academy of Live and Recorded Arts ti ìlu UK.[3]
Kíkópa rẹ̀ nínu eré tẹlifíṣọ̀nù
àtúnṣeLẹ́hìn àwọn ipa rẹ̀ nínu Holby City, Casualty, àti fiimu Babymother tó gba àmì-ẹ̀yẹ,[4] Chikezie rí àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ tó ṣe sàánsàán bíi Sasha Williams nínu As If [5] ní ọdún 2001. Nígbà tí ó di ọdún 2004, ó rí ipa míràn bi Elaine Hardy, ọ̀rẹ́bìnrin Kyle Pascoe nínu eré Footballer's Wives. Lára àwọn iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀nù rẹ̀ míràn ni 40, Judas Kiss, Free Fall àti Brothers and Sisters.
Ó kópa bíi Lisa Hallett, ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan tí ó ti yípadà sí apákan ènìyàn, apákan ère nínu "Cyberwoman", ó sì tún kópa gẹ́gẹ́ bi Tamara, adẹdẹ àlùjọ̀nú kan nínu eré Supernatural. Ní ọdún 2018, ó tún kópa gẹ́gẹ́ bi Queen Tamlin nínu Shannara Chronicles. Bẹ́ẹ̀ ló dẹ̀ kópa gẹ́gẹ́ bi Angela Ochello nínu eré tẹlifíṣọ̀nù aláṣeyọrí kan ti EbonyLife "The Governor."
Kíkópa rẹ̀ nínu sinimá àgbéléwò
àtúnṣeGẹ́gẹ́bi òṣèré fiimu, Chikezie ti kópa nínu fiimu Eragon.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Footballers Wives". Archived from the original on 9 October 2016. Retrieved 28 October 2020.
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 16 November 2020. Retrieved 28 October 2020.
- ↑ http://www.nigerialinks.com/Nollywood/chikezie.html Archived 31 October 2020 at the Wayback Machine. HOW FOOTBALLERS' WIVES STAR FOUND FAME]
- ↑ My family was so angry about me wanting to act they tricked me into leaving Britain
- ↑ Caught in the prime of life; As If Ch4