Chakhchoukha tàbí chekhechoukha jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ Algeria èyí tí wọ́n máa ń fi sẹ̀mọ́ tí wọ́n ṣe róbóróbó ṣe, sínú ọbẹ̀ tomato. Oúnjẹ yìí máa ń ní rougag kékèèké níní tí wọ́n fi marqa sínú ẹ̀ tó wà nínú ọbẹ̀ tomato.[1] Tí wọ́n bá fẹ́ se oúnjẹ yìí, wọ́n máa se semolina dough náà nínú omi oníyọ̀ títí á fi jiná, wọ́n ṣe máa wá ṣe é róbóróbó.

Chakhchoukha
Alternative namesChekhechoukha (شخشوخة)
TypeStew
CourseMain course
Place of originAlgeria
Region or stateConstantine, Batna, Biskra, Ms'sila
Serving temperatureHot
Main ingredientsChickpea, tomatoes, onions, garlic, meat, vegetables, Algerian spices
VariationsChakhchoukha Biskria, Chakhchoukhat dfar
Similar dishesZviti
Àdàkọ:Wikibooks-inline 
Chicken chakhchoukha
Algerian Chakhchoukha of Biskra

Ọbẹ̀ tomato tí wọ́n ń lò fún chakhchoukha ni wọ́n má ań se nípa lílo àlùbọ́sà, tòmátò, àti àwọn èròjà ìsebẹ̀ bí i cumin, paprika, àti harissa. Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa wá da semolina dough ọ̀hún sínú ọbẹ̀ tòmátò yìí kí àwọn èròjà ọbẹ̀ náà lè toró sínú sẹ̀mó ọ̀hún.[2]

Tí wọ́n bá fẹ́ jẹ Chakhchoukha, wọ́n máa ń lo ẹran, bí i ọ̀yà tàbí ẹran màlùú, èyí tí wọ́n máa ń se lọ́tọ̀ tí wọ́n sì máa fi ẹ̀fọ́, carrot tàbí turnip sínú ẹ̀.[3] Oríṣiríṣi ewébẹ̀ ni wọ́n máa ń fi sí inú oúnjẹ yìí.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Chakhchoukha de Biskra" (in fr-FR). vitaminedz.com. https://www.vitaminedz.com/fr/Algerie/chakhchoukha-de-biskra-3252-Articles-0-15610-1.html. 
  2. Bouksani, Louisa (1989). Gastronomie Algérienne. Alger, Ed. Jefal. p. 192.
  3. Boumedine, Rachid Sidi (2022-12-01). "Cuisines traditionnelles d'Algérie: l'art d'accommoder l'histoire et la géographie" (in en). Anthropology of the Middle East 17 (2): 48–63. doi:10.3167/ame.2022.170204. ISSN 1746-0719. https://www.berghahnjournals.com/view/journals/ame/17/2/ame170204.xml.