Chief Kivoi Mwendwa
Chief Kivoi Mwendwa (tí wọ́n bí ní ọdún 1780) fìgbà kan jẹ́ oníṣòwò ọlọ́nà jínjìn, tó ń gbé ní ìlú tí wọ́n ń pè ní Kitui, ní òde-òní. Kivoi gbajúmọ̀ jù lọ fún ṣíṣe amọ̀nà àwọn ajínhìnrere lọ sí ìlú Kenya, lẹ́yìn tó ṣamọ̀nà àwọn ajíhìnrere ti ilẹ̀ Germany, ìyẹn Johann Ludwig Krapf àti Johannes Rebmann ti ìjo Anglican Church Missionary Society (CMS). Lásìkò àwọn ìrìn-àjò náà ni Rebmann àti Krapf ní ìfojúkojú pẹ̀lú Mount Kenya.[1]
Chief Kivoi Mwendwa | |
---|---|
Chief Kivoi Mwendwa, 1849 | |
Ọjọ́ìbí | 1780s Kitui, Kenya |
Aláìsí | Tana River | 19 Oṣù Kẹjọ 1852
Iṣẹ́ | Trader |
Ìsọníṣókí
àtúnṣeKivoi ṣalábàápàdé àwọn ará ilẹ̀ Europe méjì náà ní Mombasa, ó sì rin ìrìn-àjò pẹ̀lú wọn lọ sí Ukambani. Ní ọjọ́ 3 December ọdún 1849, wọ́n jẹ́ aláwọ̀ funfun àkọ́kọ́ tó máa kọ́kọ́ rí.[2]
Àmọ́ ní Europe, àwọn ènìyàn ò gbàgbọ́ pé wọ́n rí orí-òkè yìí, wọ́n sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Chief Kivoi ṣe ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Lárúbáwá ní ìlú Voi, tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pe ìlú náà, nítorí ibẹ̀ ló kọ́kọ́ ti dúró, kí ó tó wọ Mombasa.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Finke, Jens. "Kamba – Colonial History". bluegecko.org. Retrieved 27 March 2018.
- ↑ Okoth, Assa (2006). A History of Africa. 1. East African Educational Publishers. ISBN 9789966253576. https://books.google.com/books?id=6knAMseFPpIC&dq=discovery+of+Mount+Kenya+kivoi&pg=PA81.