Chike
Chike-Ezekpeazu Osebuka tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1993 tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ CHIKE, jẹ́ akọrin, òǹkọ̀wẹ́, akọrinsílẹ̀ àti òṣèré orílẹ̀-èdè Naijiria. Chike jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn akópa nínú ìdíje àwọn Akọrin Project Fame West Africa lẹ́yín ìdíje yìí ni ó gba ipò kejì ni àṣekágbá ìdíje The Voice Nigeria.[1] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣèré fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí ó kópa nínú fíìmù Àgbéléwò BATTLEGROUND èyí tí ó wà lójú ìwòran African Magic inú eré-oníṣe àgbéléwò yìí ni Chike tí ṣe ẹ̀dá ìtàn tí a mọ sí Mayowa.[2]
Chike | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Chike-Ezekpeazu Osebuka |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | Chike |
Ọjọ́ìbí | 28 Oṣù Kínní 1993 Lagos, Lagos State, Nigeria |
Irú orin | Highlife, RnB |
Occupation(s) | Singer, Songwriter, Actor |
Instruments | Vocals |
Years active | 2009–present |
Associated acts | Phyno, Ric Hassani, Simi, Mayorkun, Gyakie |
Ìbèrẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àti ẹ̀kọ́
àtúnṣeChike jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Onitsha, ní Ìpínlẹ̀ Anámbra, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ mẹ́rin tí àwọn òbí rẹ̀ bí.
Ipa pàtàkì ni ìdílé Chike kó nínú ìpinnu rẹ̀ láti di olórin.[3] Ó gboyè ẹ̀kọ́ ní Covenant University nínú Computer Engineering[4]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeÌdíje Project Fame
àtúnṣeChike kópa nínú ìdíje project fame, ó tiraka láti wọ ipò kẹwàá.[5]
Ìdíje The Voice Nigeria
àtúnṣeChike tún kópa nínú ìdíje The Voice of Nigeria. Ó sì gba ipò kejì.[6][7]
Lẹ́yìn ìdíje The Voice Nigeria
àtúnṣeLẹ́yìn ìdíje The Voice Nigeria níbi tí ó ti gba ipò kejì lẹ́yìn àṣekágbá ìdíje náà. Òun àti àwọn tí ó dé ipile ẹlẹ́ni mẹ́wàá ni wọ́n gbà wò ilé ìṣe onídárayá universal republic. Ó ṣe àgbéjáde orin àkọ́kọ́ FANCY U ni December 2016 lábẹ́ akoso Universal Republic. Chike jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn aṣojú fún Airtel Nigeria pẹ̀lú àwọn méje tí ó dé ipile ẹlẹ́ni mẹsan-án.[8]
2017-2019
àtúnṣeNí ọdún 2017, chike bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣèré fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí ó kópa nínú fíìmù àgbéléwò BATTLEGROUND èyí tí ó wà lójú ìwòran African Magic.[9] Nínú fíìmù àgbéléwò yìí ni Chike tí ṣe àgbéjáde ìwà ẹ̀dá ìtàn Mayowa Badmus. Ní November 2017, Chike kúrò ní Universal Republic láti dá dúró. Ní oṣú kejí, ọdún 2018, ó gbé orin àdákọ rẹ̀ jáde tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Beautiful People"[10]
2020
Ní ọdún 2020, Chike ṣe àgbéjáde àkójọpọ̀ orin mẹ́rìnlá nígbà tí wọ́n gbà á gẹ́gẹ́ bí àlejò pàtàkì ni ètò àgbéléwò big brother lásìkò kónílé-ó-gbélé.
Àmì-èyẹ rẹ̀
àtúnṣeYear | Award | Category | Recipient | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2021 | Net Honours | Most Played RnB Song | "Running to You" (featuring Simi)|style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | [11] |
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Isaac, Michael (2020-02-29). "SPOTLIGHT: Meet The Creative Mind Of Actor, Singer Chike". Information Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-06.
- ↑ "Chike-Ezekpeazu Osebuka". IMDb. Retrieved 2020-11-06.
- ↑ "The Voice Nigeria". The Voice Nigeria. Archived from the original on 2017-02-03. Retrieved 2017-12-21. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "7 Famous Nigerian Musicians Who Studied At Covenant University (Photos) - Opera News". za.opera.news. Archived from the original on 2021-03-10. Retrieved 2020-11-06.
- ↑ Izuzu, Chidumga. "Project Fame 8: One evicted, judges pull surprise as race for prize gets intense [Video"] (in en-US). Archived from the original on 2017-05-25. https://web.archive.org/web/20170525055716/http://pulse.ng/movies/project-fame-8-one-evicted-judges-pull-surprise-as-race-for-prize-gets-intense-video-id4125674.html.
- ↑ Editor, Online (2016-06-18). "The Voice Nigeria Chike ‘Ranking’ Goes to Battle" (in en-US). THISDAYLIVE. http://www.thisdaylive.com/index.php/2016/06/19/the-voice-nigeria-chike-ranking-goes-to-battle/.
- ↑ Isaac, Michael (2020-02-29). "SPOTLIGHT: Meet The Creative Mind Of Actor, Singer Chike". Information Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-22.
- ↑ GossipBoyz (2017-03-04). "AUDIO+VIDEO: The Voice Nigeria’s First Runner Up, Chike debuts new song – 'Fancy U' [DOWNLOAD]". GossipBoyz (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-01-28. Retrieved 2021-01-22.
- ↑ Battleground: Africa Magic (TV Series 2017– ) - IMDb, retrieved 2021-01-22
- ↑ "Chike - Beautiful People (Prod by Doron Clinton) « tooXclusive". tooXclusive (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-01-28. Archived from the original on 2021-01-28. Retrieved 2021-01-22.
- ↑ "Net Honours - The Class of 2021". Nigerian Entertainment Today (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-09-07.