China State Shipbuilding Coorporation

Àwọn ilé-iṣẹ́ Ìpínlẹ̀ China tí wọ́n ṣe ọkọ̀ ojú-omi akérò ní ilẹ̀ China tí a mọ̀ sí (CSSC) ni ó jẹ́ ilé iṣẹ́ aláfọwọ́ sowọ́pọ̀ tí wọ́n ń kọ́ ọkọ̀ ojú-omi akérò ní ilẹ̀ China.

China State Shipbuilding Corporation Limited
TypeState owned
Predecessor中国船舶工业总公司 (1982–1999)
中国船舶工业集团有限公司 (1999–2019)
HeadquartersHaidian District, Beijing, China
Area servedWorldwide
Key peopleZhang Yindgai (Chairman)
IndustryShipbuilding, defense
Employees310,000
ParentSASAC
China CSSC Holdings Limited
中国船舶工业股份有限公司
TypeSubsidiary
Founded1998
HeadquartersShanghai, China
Area servedWorldwide
Key peopleDong Qiang (董强) (Chairman)
IndustryShipbuilding
ParentChina State Shipbuilding Corporation
WebsiteChina CSSC Holdings Limited

Agbékalẹ̀ rẹ̀

àtúnṣe

CSSC ni ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀ka mẹ́wàá nílé iṣẹ́ ọmọ ogun ní orílẹ̀-èdè China, [1] ni ó ní àyè ìgbọ́kọ̀ ojú-omi sí, ó ní oríṣiríṣi irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń ṣe ọkọ̀ ojú-omi tuntun yálà ti àwọn ọmọ ogun ni tàbí ti ìkérò lásán. CSSC ni àwọn lààmì-laakaàti gbajú-gbajà àwọn ọláọ́pọlọ tí wọ́n mọ̀ nípa ṣíṣe ọkọ̀ ojú-omi ní orílẹ̀-èdè China, àwọn bí :Dalian Shipbuilding Industry Company, Jiangnan Shipyard, Hudong–Zhonghua Shipbuilding, Guangzhou Huangpu Shipbuilding[2] àti Guangzhou Wenchong Shipyard.[3]. Wọ́n gbé diẹ̀ lára àwọn ilé-iṣẹ́ kékèké tí ó wà lábẹ́ àjọ wọn bíi CSSC Holdings Limited sì ọjà pàṣípàrọ̀ ti Shangai, tí wọ́n sì tún ti ara ibẹ̀ rí àwọn ilé-iṣẹ́ Shangai Waigaoqiao Shipbuilding sí abẹ́ àkóso wọn.[4]

Ìtàn ní ṣókí

àtúnṣe

Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀

àtúnṣe

Ní ọdún 1964, wọ́n da ilé-iṣẹ́ Sixth Ministry of Machine Building sílẹ̀[5] láti lè ma fi ṣakóso gbogbo àwọn ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ọkọ̀ ojú-omi jáde ní ilẹ̀ China, tí ó sì jẹ́ wípé gbogbo ọkọ̀ wọn tí wọn ń ṣe jáde ni ó jẹ́ ti àwọn jagun-jagun.[6] In July 1982,[7] Wọ́n da ilé-iṣẹ́ yí sílẹ̀ láti fi ṣe atúntò sí ilé-iṣẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ China ni, tí Won sì ṣe àyípadà rẹ̀ sí China State Shipbilding Cooperation.[6] Àjọ CSSC yí wà lábẹ́ ìṣàkóso Ìpínlẹ̀ amọ́ wọ́n fún wọ́n ní ànfaní láti ma ṣiṣẹ́ kí ìdàgbà-sókè ó lè bá ọrọ̀ aje orílẹ̀-èdè wọn.[8] Ní ọdún 1992, àjọ CSSC yí àfojúsùn wọn padà sí wọ́n ma ṣe ohun tí tẹrú-tọmọ ó lè lò ní orílẹ̀-èdè China, tí ìdá ọgbàọ́rin nínú ohun tí wọ́n ń pèsè jáde ṣe jẹ́ ohun tí àwọn ará ìlú lè jànfàní rẹ̀. Ìgbà tí yóò fi di ọdún 1993, wọ́n ti ń ta ìlàjì nínú àwọn ohun tí wọ́n ń pèsè sí ilẹ̀ òkèrè.[9]

Àyípadà tí ó dé bá CSIC

àtúnṣe

Níparí ọdún 1990, ṣíṣàtúntò tí wọ́n ṣàtúntò ètò ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè China mú kí ìjẹ gàba ilé-iṣẹ́ àwọn kànrìn kànrìn ènìyàn tí wọ́n lẹ́nu lọ́rọ̀ ó fọ́ká yángán, tí àwọn oríṣiríṣi aládàáni tí wọ́n jẹ́ mékúnù náà ó bẹ̀rẹ̀ sí ń da sí pípèsè nkan oríṣiríṣi jáde láti lè mú kí ìta-kangbọ̀n ó wáyé níbi pípèsè nkan jáde ní orílẹ̀-èdè China.[10][11] Nígba ó di inú oṣù keje ọdún 1999, wọ́n yọ China Shipbuilding Industry Corporation kúrò lára àjọ CSSC;[11] tí wọ́n sì pin àwọn ilé-iṣẹ́ àgbàọ́kọ̀-jáde sí ẹkún ò jẹkùn, amọ́ tí CSSC ṣe ń darí gbogbo wọn pàá pàá jùlọ ní apá àríwá ati àárín gbùngbùn ilẹ̀ China. [12] àjọ CSSC náà tún ń jábọ̀ fún ẹ̀ka ọba ti State-owned Assets Supervision and Administration Commission (SASAC).[13] [12][14]


Ẹ tún lè wo àwọn àyọkà wọ̀nyí

àtúnṣe

Àwọn itọ́ka sí

àtúnṣe
  1. Allen-Ebrahimian, Bethany (2020-06-24). "Defense Department produces list of Chinese military-linked companies, 20 years after mandate". Axios (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-24. 
  2. "Shipyard - CSSC GUANGZHOU HUANGPU SHIPBUILDING CO., Ltd". 
  3. "Shipyard - Guangzhou Wenchong Shipyard (New Buildings)". 
  4. "About Us". Archived from the original on 2021-07-25. Retrieved 2021-08-24. 
  5. Collins and Grubb, pg. 6
  6. 6.0 6.1 Medeiros et. al, pg. 113
  7. Collins and Grubb, pg. 7
  8. Collins and Grubb, pg. 5
  9. Collins and Grubb, pg. 8
  10. Collins and Grubb, pg. 9-10
  11. 11.0 11.1 Medeiros et. al, pg. 114
  12. 12.0 12.1 Medeiros et. al, pg. 117
  13. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named cms-1_9
  14. Medeiros et. al, pg. 121

Àwọn orísun

àtúnṣe


Àwọn àsopọ̀ ìta

àtúnṣe