Christopher Ofili (A bí i ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù ọ̀wàwà ọdún 1968 ó jẹ́ ayàwòrán ilẹ̀ Britain, tí ó gbajúmọ̀ fún àwọn iṣẹ́ ẹ rẹ̀ tó máa ń ní ìgbẹ́ erin nínú. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Turner Prize, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwon ọ̀dọ́ tó jẹ́ ayàwòrán ní ilẹ̀ Britain. Láti ọdún 2005, ni Ofili ti ńṣiṣẹ́ ní Trinidad and Tobago, níbi tí ó ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ní ìlú Port of Spain. Bákan náà ni ó sì ti gbé ní London àti Brooklyn, tí ó sì ti ṣiṣẹ́ níbẹ̀.[1]

Chris Ofili
Ilẹ̀abínibí British
Pápá Painting
Training Chelsea School of Art
Royal College of Art
Iṣẹ́ No Woman No Cry (1998),
The Adoration of Captain Shit and the Legend of the Black Stars (1998),
The Upper Room (2002)
Ẹ̀bùn 1998 Turner Prize
Red Bird - watercolour on paper

Ofili ti lo rẹ́síìnì, ilẹ̀kẹ̀, òróró tí wọ́n lò fún ìyàwòrán, ìgbẹ́ erin àti àwọn àwòrán oníhòhò tí ó rí ní ìwé-ìròyìn.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ìlú Manchester, ní England ni wọ́n bí Ofili sí, sínú ìdílé May àti Michael Ofili tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2] Nígbà tí ó wà ní ọmọdún mọ́kànlá, bàbá rẹ̀ fí ẹbí rẹ̀ sílẹ̀ ó si padà sí ilẹ̀ Nàìjíríà.[3] Ofili kàwé fúngbà díẹ̀ ní St. Pius X High School tó wà fún àwọn ọkùnrin nìkan, ó sì tún lọ sí Xaverian CollegeVictoria Park, Manchester.[4] Ofili parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Tameside CollegeAshton-under-Lyne lágbègbè Greater Manchester[3] ó sì tún kàwe ní London, ní Chelsea School of Art láti ọdún 1988 wọ 1991. Bákan náà ni ó lọ Royal College of Art láti ọdún 1991 wọ 1993. Ní ọdún 1992, ó gba ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti kàwé ní Universität der Künste Berlin.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe