Cillian Murphy ( /ˈkɪliən/ KILL-ee-ən;[1] tí a bí ní ọjọ́ kàrúnlélógún oṣù Kàrún ọdún 1976) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Ireland. Ó ṣeré fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú eré Enda Walsh ltí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Disco Pigs ní ọdún 1996. Àwọn eré míràn tí ó ti farahàn ni 28 Days Later (2002), nínú Intermission (2003), Red Eye (2005), The Wind That Shakes the Barley (2006), Sunshine (2007). Ó seré nínú eré Breakfast on Pluto (2005), èyí tí ó mú kí wọ́n yán kún ara àwọn ti ó tó sí Golden Globe Award.

Cillian Murphy
Murphy ní Berlinale 2017
Ọjọ́ìbí25 Oṣù Kàrún 1976 (1976-05-25) (ọmọ ọdún 48)
Cork, Ireland
Iṣẹ́Actor
Ìgbà iṣẹ́1996–present
WorksFull list
Olólùfẹ́
Àwọn ọmọ2

Murphy bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Christopher Nolan ní ọdún 2005, ó kó ipa Dr. Jonathan Crane / Scarecrow nínú eré The Dark Knight Trilogy (2005–2012), nínú Inception (2010), Dunkirk (2017), àti gẹ́gẹ́ bi J. Robert Oppenheimer nínú Oppenheimer (2023). Ó gbajúmọ̀ si nígbà tí ó ṣeré gẹ́gẹ́ bi Tommy Shelby nínú eré BBC tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Peaky Blinders (2013–2022) àti nígbà tí ó ṣeré nínú A Quiet Place Part II (2020).

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Grainger, Laura (2023-07-04). "'Cillian': The correct pronunciation and meaning behind Oppenheimer star's name". irishstar (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-25.