Claire Edun, tí a mọ̀ sí Òyìnbó Princess,[2] jẹ́ òṣèré Nollywood ọmọ Ilẹ̀-gẹ̀ẹ́sì. Ó gbajúmọ̀ fún sísọ èdè píjìnì ti Nàìjíríà[3], èyí tí ó padà ṣokùn fa ipa tí ó kó nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Authentic Tentative Marriage (ATM) ní ọdún 2016, tí olùdarí eré náà n ṣe Lancelot Imasuen.[4]

Claire Edun
Ọjọ́ìbí1984 (ọmọ ọdún 40–41)
Winchester, Hampshire, England
Orílẹ̀-èdèBritish[1]
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́2015–present
Olólùfẹ́
Richard Edun (m. 2012)
separated in 2018

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Edun ni ẹni tí a bí sí ọwọ́ àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ará Brítànì, ó sì ní ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ náà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó fi rí iṣẹ́ kan gẹ́gẹ́ bi òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú, èyí tí ó fun ní ànfàní láti káàkiri àgbáyé, ó bẹ̀rè sí ní fẹ́ràn ilẹ̀ Áfríká, pàápàá jùlọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó di ìlúmọ̀ọ́ká ní ọdún 2015 lẹ́hìn tí ó fi fídíò ara rẹ̀ hàn lóri ẹ̀rọ ayárabíàṣá Faceebook níbi tí ó ti ń sọ èdè píjìnì ti Nàìjíríà pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Èyí ni olùdarí eré Lancelot Imasuen rí tí ó fi fun ní ipa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ (ATM) Authentic Tentative Marriage.[5] Ó kó ipa gẹ́gẹ́ bi ọmọbìnrin òyìnbó tí ó wá sí Nàìjíríà láti fẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí ó n wá láti gbé ní ilẹ̀ Brítànì.[6]

Àwọn eré tí ó ti kópa

àtúnṣe
  • (ATM) Authentic Tentative Marriage (2016)

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "English actress who is a Nigerian film star". BBC News. 11 May 2016. Retrieved 7 October 2017. 
  2. Nài
  3. ̀jí
  4. ̀ la
  5. ílẹ
  6. ède